Òmìnira Yorùbá! Ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn fẹ́ẹ́ wáyé lónìí nílu Ìgbòho - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 11, 2021

Òmìnira Yorùbá! Ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn fẹ́ẹ́ wáyé lónìí nílu Ìgbòho


Pupọ awọn ọmọ Yoruba ni wọn ti gbaradi lati ṣe ifẹhonuhan miran lonii lati beere fun itusilẹ Oloye Sunday Adeyẹmọ ti awọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho to wa lọgba ẹwọn niluu Kutọnu, orilẹ-ede olominira Bẹnnẹ.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni nibẹ ni wọn tun ti fẹẹ bẹrẹ iwọde fun ominira idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa, iyẹn Yoruba Nation.

Bẹ o ba gbagbe, iwọde naa ti waye lawọn ipinlẹ bii Ekiti, Ọyọ, Ondo, Ogun, Ọṣun ati Eko.

Ọgbẹni Ọlayọmi Koiki to jẹ agbẹnusọ Igboho lori ọrọ iroyin nigba to n sọrọ sọ pe ilu abinibi Oloye Sunday Igboho ni iwọde naa yoo ti waye bẹrẹ lati aago mẹwaa aarọ oni.

Agboole Aladikun to wa ni Modakẹkẹ, Igboho, nipinlẹ Ọyọ ni Oloye Sunday Adeyẹmọ ti wa.

Igboho is from Aladikun compound in Modeke, Igboho, Oyo state.

O ti n lọ si bi oṣu meji bayii ti ọkunrin naa ti wa lọgba ẹwọn Kutọnu nigba yi ọwọ tẹ ẹ ni papakọ ofurufu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI