Àwọn ọlọ́kadà bọ́ sáyé l'Abẹ́òkúta, àjọ aláànú Olumide Adérìnókùn ṣagbátẹrù epo ọ̀fẹ́ fún wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 11, 2021

Àwọn ọlọ́kadà bọ́ sáyé l'Abẹ́òkúta, àjọ aláànú Olumide Adérìnókùn ṣagbátẹrù epo ọ̀fẹ́ fún wọn


Ṣẹnkẹn bayii ni gbogbo awọn ọkọkada jakejado ijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta (Abeokuta North) n dun lonii, ọjọ Aje, Mọnde, nigba ti ajọ alaanu kan ti wọn pe ni Olumide and Stephanie Aderinokun Foundation ṣagbatẹru epo ọfẹ fun gbogbo wọn.

Ẹlẹẹkarun-un iru ẹ ree ti a gbọ pe ajọ naa yoo maa gbe kalẹ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

AWIKONKO rii gbọ pe awọn ọkọkada to wa ni ijọba ibilẹ Guusu Abẹokuta, iyẹn Abeokuta South naa yoo jẹ anfaani yii lọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọla.

Pupọ awọn ọkọkada to sọrọ ni wọn dupẹ lọwọ awọn alakoso ajọ alaanu naa, paapaa oludasilẹ rẹ, Oloye Olumide Aderinokun fun oju aanu to fi wo wọn.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI