Wọ́n ju àwọn ọmọ 'Yahoo' méjìdínlógún sẹ́wọ̀n lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 22, 2021

Wọ́n ju àwọn ọmọ 'Yahoo' méjìdínlógún sẹ́wọ̀n lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo


Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorilẹ-ede yii, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ẹka tipinlẹ Ẹnugu ti kede sita wi pe gendekunrin mejidinlogun kan ti wọn ko niṣẹ meji ju jibiti ori ayelujara lọ ti dero il-ẹjọ, ati pe ile-ẹjọ naa ti ju gbogbo wọn sẹwọn pẹlu iṣẹ aṣekara.

Wọn ni ile-ẹjọ giga tijọba apapọ to wa nilu Ẹnugu ni gbogbo wọn ti gba idajọ wọn lọjọ kẹrindinlogun, ọjọ kẹtadinlogun ati ọjọ kejidinlogun oṣu yii, ti wọn si gba idajọ to tọ si ẹsun kọọkan ti wọn fi kan gbogbo wọn.

Ko si ẹsun meji ti a gbọ pe wọn fi kan wọn, to yatọ si lilu jibiti ori ayelujara, iyẹn nipa gbigba owo lọna ti ko tọ.
 
Lara awọn mejidinlogun naa ni: Mba Rocks, Nzube Arinze, Osude Ebube Sunday, Kingsley Onyeoji Chukwuemeka, Nwoke Arinze Daniel, Nwobodo Emmanuel, Chukwuemeka Emmanuel Ojara, Osinachi Charles Chinaza, Ezediegwu Innocent, Chima Bright Ojara, Onochie JohnPaul Arinze, Ude Ifeanyi ati Chisom Nworah.

Awọn yooku ni: MacAnthony Ijezie Chibuike, Ali Chiebere Shedrach, Obinna William, Chukwujekwu Michael Nnamdi, Nwokike Arinze Daniel ati Johnson Chima Madueke.

Onidajọ F.O.G Ogunbanjọ lo kọkọ ju awọn marun-un sẹwọn lọjọ kẹrindinlogun, to si tun ju awọn mẹta miran sẹwọn lọjọ kejidinlogun, oṣu yii, nigba ti Onidajọ I.M Buba ju awọn mẹwaa yooku sẹwọn lọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii kan naa.
 
Diẹ ree lara awọn ti wọn ju sẹwọn naa:












No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI