Ọkàn mí balẹ̀ lórí Ọmọọba Fágbèmí lórí ìpàdé àlàáfíà rẹ̀ - Tinubu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 20, 2021

Ọkàn mí balẹ̀ lórí Ọmọọba Fágbèmí lórí ìpàdé àlàáfíà rẹ̀ - Tinubu


Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Bọla Ahmẹd Tinubu, ti sọ pe ọkan oun balẹ lori alaga tuntun fẹgbẹ oṣelu naa, ẹka tipinlẹ Kwara ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Ọmọọba Sunday Fagbemi.
 
Laipẹ yii ni Ọmọọba Fagbemi ṣabẹwo si Tinubu nile rẹ to wa nilu Abuja, nibi to ti lọ fi bi nnkan ṣe n lọ lakooko yii ninu ẹgbẹ naa to o leti, paapaa fun ti ibura fun un to fẹẹ waye ni kopẹkopẹ.
 
Ṣaaju akoko yii la gbọ pe Fagbemi ti ṣabẹwo si alaga fidihẹ tẹlẹri fẹgbẹ naa, Oloye Bisi Akande nile ẹ to wa nilu Ila Ọrangun, ipinlẹ Ọṣun.

Awọn abẹwo wọnyii, ko ṣẹyin lati wa ọna abayọ si wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Kwara, ki gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ si wa ni iṣọkan.
 
Nigba to n sọrọ, Aṣiwaju Tinubu sọ pe ọkan oun balẹ gidi lori Ọmọọba Fagbemi pẹlu awọn igbesẹ to n gbe lati wa ọna lati pana aawọ to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa, bẹẹ lo gba gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lamọran lati wa ni iṣọkan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI