Adérìnókùn kẹ́dùn ìpapòdà Olówu tìlú Òwu Abẹ́òkúta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 16, 2021

Adérìnókùn kẹ́dùn ìpapòdà Olówu tìlú Òwu Abẹ́òkúta


Akinruyiwa tilu Owu nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, Oloye Olumide Aderinokun ti ṣabẹwo ibanikẹdun si Aafin Olowu tilu Owu lori ipapoda Kabiyesi wọn, Ọba Adegboyega Dosunmu, Amọroro keji, ẹni to waja lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii.
 
Ọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọsẹ yii ni igbimọ afọbajẹ tilu Owu ṣẹṣẹ kede sita fun gbogbo eeyan nipa ipapoda kabiyesi, lẹyin ti ayẹwo ti fidi rẹ mulẹ wi pe kabiyesi ti lọ ba awọn baba nla rẹ.

Nigba to n sọrọ nibi abẹwo ibanikẹdun ọhun, Oloye Aderinokun ṣapejuwe Ọba Adegboyega Dosunmu gẹgẹ bi olutọna sibi idagbasoke ati ọba ti iṣọkan, ifẹ ati alaafia jẹ logun, to si ni iku naa ba gbogbo ọmọ Naijiria, paapaa awọn ọmọ ilu Owu lọkan jẹ gidi.
 
Aderinokun sọ pe asiko ti orilẹ-ede yii nilo rẹ julọ lo fi aye silẹ lati lọ jẹ ipe awọn baba nla rẹ lajulẹ ọrun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI