Wọ́n bá òku ọmọ gbajúmọ̀ báálẹ̀ àti olólùfẹ́ ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ nínú mọ́tò, lẹ́yìn ìbálòpọ̀ gbígbóná - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, December 16, 2021

Wọ́n bá òku ọmọ gbajúmọ̀ báálẹ̀ àti olólùfẹ́ ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ nínú mọ́tò, lẹ́yìn ìbálòpọ̀ gbígbóná


Ileeṣẹ eleto aabo So-Safe Corp nipinlẹ Ogun ti sọ pe awọn ti ṣalabapade oku awọn meji kan ninu mọto, lẹyin ti wọn ni ibalopọ gbigbona tan nijọba ibilẹ Ipokia.
 
AWIKONKO gbọ pe iwaju ile kan to wa ni Agọ Egun nilu Idiroko la gbọ pe wọn ti ri mọto Toyota Camry ti nọmba idanimọ rẹ jẹ LND 223 BV, eyi ti awọn mejeeji naa ku si.
 
Nnkan bi aago mẹjọ alẹ, ọjọ Ajẹ, Mọnde, ọsẹ yii la gbọ awọn oṣiṣẹ So-Safe ti ẹkun Idiroko ṣalabapade mọto naa, ti wọn si ri oku awọn eeyan naa nibẹ.
 
Iwadii ti wọn ṣe fi han pe Azeez Ilias, ẹni ọdun mẹtadinlogoji to jẹ ọmọ ọkan lara awọn baalẹ nilu Ipokia lo ni mọto naa, oun pẹlu ololufẹ ikọkọ rẹ ti wọn pe orukọ tirẹ ni Deborah ni wọn jọ ku sinu mọto yii nihooho ọmọluabi, lẹyin ti wọn laṣepọ karakara tan.

A gbọ pe inu kọta to wa niwaju ile Deborah, iyẹn nibi ti wọn gbe mọto yii si lati laṣepọ ni wọn ti ba aṣọ Azeez, ti a si gbọ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ iru iku to pa awọn mejeeji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI