Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq loni, Ọjọ Ẹti, Furaidee ti gbe ọpa aṣẹ fun Ẹmir tilu Patigi tuntun, Alaaji Mohammed Kawu Kudu, to si tun gba a lamọran lati lo ipo naa fun igbelarugẹ alaafia, ifẹ, ati ilọsiwaju awọn eeyan rẹ lapapọ.
Alaaji Kawu Kudu ni Ẹmir tilu Patigi kẹrinla latigba ti wọn ti tẹ ilu naa do. Ọgbọn ọjọ, oṣu keje, ọdun yii ni wọn yan an sipo naa, lẹyin ti Ẹmir ana, Saadu Kawu Haliru papoda, lẹyin ọdun mẹrindinlaadọta lori ipo.
Nibi ayẹyẹ gbigba ọpa aṣẹ naa, nigba to n sọrọ, AbdulRazaq dupẹ lọwọ awọna fọbajẹ labẹ Ẹmir tilu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Zulu-Gambari lori ọna ti wọn n gba lati maa jẹ ki alaafia jọba laaarin wọn.
No comments:
Post a Comment