Babaláwo tó bí ọmọ ọ̀ọ́dúnrún àti ìyàwó mọ́kàndínlọ́gọ́ta ti jáde láyé o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, December 16, 2021

Babaláwo tó bí ọmọ ọ̀ọ́dúnrún àti ìyàwó mọ́kàndínlọ́gọ́ta ti jáde láyé o


Oloye Simon Odo, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Ọmọ Eṣu, iyẹn 'Son of Satan' nipinlẹ Enugu ti jade laye lẹni ọdun mẹrinlelaadọrin, 74.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe Oloye Odo ku lẹyin aisan rampẹ ti wọn lo daa dubulẹ lati bi ọsẹ meloo kan sẹyin.
 
Iyawo mọkandinlọgọta, ọmọ ati ọmọ-ọmọ to le ni ọọdunrun la gbọ pe baba yii fi silẹ saye lọ, ti wọn si ti sinku rẹ.

Eyi to je kayeefi nipa bi wọn se sinku Oloye Odo ni bi a ṣe gbọ pe ṣe ni wọn sin oku rẹ pẹlu mọto bọginni to wa lori iṣẹ.

Ọkan lara awọn ọmọ baba yii ti wọn pe ni Emeka Odo, nigba to n bawọn akọroyin sọrọ sọ pe ki baba wọn to ku, lo ti ṣe ikilọ wi pe wọn ko gbọdọ sin oku oun si itẹku, bi ko ṣe pe ile ni ki wọn sin oun si.

Yatọ si eyi, iṣẹ babalawo pọmbele ni oloogbe yii yan laayo ko to ku, ilu Aji to wa nijọba ibilẹ Ariwa Igbo-Eze, ipinlẹ Enugu lo ti wa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI