Ìjọba Kwara fìtàn tuntun balẹ̀ lórí ètò ìdàgbàsókè ọlọ́dún mẹ́wàá tí wọ́n ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 16, 2021

Ìjọba Kwara fìtàn tuntun balẹ̀ lórí ètò ìdàgbàsókè ọlọ́dún mẹ́wàá tí wọ́n ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀


Lasiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan, orin idupẹ lawọn ara, ọmọ bibi ati olugbe ipinlẹ Kwara n kọ fun ijọba lori bi wọn ṣe fi eto idagbasoke alailẹgbẹ ọlọdun mẹwaa lọlẹ.
 
Yatọ awọn ọmọ ipinlẹ naa to n dupẹ lọwọ Gomina wọn, AbdulRazaq, ijọba orilẹ-ede yii, ajọ agbaye, United Nations Development Programme, UNDP naa tun gbe oṣuba kare fun gomina yii ati iṣakoso rẹ lori ọna to n gba mu idagbasoke wọle sipinlẹ ọhun.
 
Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni fi eto ọhun ti wọn pe ni 10-year Sustainable Development Plan (SDP) lọlẹ, eyi ti akanṣe iṣẹ idagbasoke yoo ti maa waye lẹsẹ-ẹsẹ, lai ni idiwọ tabi idena kankan ninu.
 
Eto naa la gbọ pe gbogbo ẹka to nii ṣe pẹlu idagbasoke ni yoo ni imọlara ilọsiwaju to ba ti ode oni mu. Lara rẹ si ni opo mẹrin ti wọn pe ni Institutional Reforms, Economic Development, Social Development, ati Infrastructural Development.

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq nigba ot n sọrọ jẹ o di mimọ pe ipinu oun ni lati rii pe idagbasoke ba eto ẹkọ, eto ilera, eto aabo, igbokegbodo ọkọ, idagbasoke igberiko ati agbegbe, idọti didanu, ọrọ awọ ọdọ, irolagbara awọn obinrin, atawọn miran.
 
Diẹ ree lara bi eto ọhun ṣe lọ si














No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI