Wòlíì Ayọ̀délé fún màma rẹ̀ ní mọ́tò bọ̀gìnnì àti ilé tuntun lọ́jọ́ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, December 11, 2021

Wòlíì Ayọ̀délé fún màma rẹ̀ ní mọ́tò bọ̀gìnnì àti ilé tuntun lọ́jọ́ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀


Ṣe ni idunnu ṣubu lu ayọ laipẹ yii, nigba ti gbajugbaja Wolii Ọlọrun nni, Primate Elijah Ayọdele fun mama rẹ, Arabinrin Margaret Ayọdele ni mọto bọginni ati ile tuntun lọjọ ayẹyẹ ọjọ ibi mama naa.

Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church, to wa nilu Eko naa la gbọ pe ẹlẹẹkeji ree ti yoo maa fun mama rẹ, to ṣayẹyẹ ọjọ ibi ọgọrin ọdun loke eepe lọjọ diẹ sẹyin.

Wolii Ayọdele sọ pe boun ba fun mama naa ni gbogbo ile aye yii, o ju bẹẹ lọ nitori pe ẹkọ toun ri kọ lara rẹ lo n ṣe anfaani foun titi di akoko yii.

Bakan naa ni Wolii Ayọdele tun fi ẹbun mọto bọginni ta egbọn rẹ, Arabinrin Dupẹ Akinfenwa lọrẹ lati fi mọ riri rẹ.

Diẹ ree lara fọto bi nnkan ṣe lọ si lọjọ naa.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI