'Born Photo', gbajúgbajà ayàwòrán n'Íbàdàn kú lójijì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 27, 2021

'Born Photo', gbajúgbajà ayàwòrán n'Íbàdàn kú lójijì


Bi kii ba a ṣe ti iku to mu gbajugbaja ayaworan kan nilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ lọ lojiji ni, oni tii ṣe  ọjọ Aje, Mọnde ni ayaworan naa, Alagba David Owolabi Ọṣitẹlu ko ba pe ẹni ọdun mẹrindinlaadọrun loke eepẹ.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe wakati mẹrinlelogun lo ku ki baba yii pe ọdun tuntun, ko to di pe iku mu lọ.
 
Odu ni Alagba David Owolabi Ọṣitẹlu, kii ṣaimọ foloko lagbooole awọn to n ya aworan, paapaa bi wọn ṣe lo ti loju oogun lakooko ijọba ologun lorileede yii.
 
Inu il aworan rẹ to wa ni Isalẹ Osi la gbọ pe baba naa dakẹ si.
 
Awọn ọmọ, ọmọ-ọmọ la gbọ pe baba yii fi silẹ saye lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI