Ìdí pàtàkì tí mo ṣe kọ Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀ sílẹ̀ - Olorì Sílẹ̀kùnọlá - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, December 24, 2021

Ìdí pàtàkì tí mo ṣe kọ Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀ sílẹ̀ - Olorì Sílẹ̀kùnọlá


Olori Ọọni Ifẹ, Ẹfanjẹlisti Naomi Ṣilẹkunọla Ogunwusi, ti kede pe oun ki i ṣe iyawo lọọdẹ Ọọni Adeyẹye mọ, bi ko ṣe Olori gbogbo eeyan ati Iya Tadenikawo.

Ninu ọrọ ti Naomi fi sori ikanni ayelujara rẹ laipẹ yii lo ti sọ pe:
“Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun otitọ rẹ laarin ọdun mẹta sẹyin ninu igbeyawo mi. Ninu irinajo ẹda, ki i ṣe bo ba ṣe pẹ to, bi ko ṣe bo ba ṣe dara si.

“Pẹlu igbagbo ati ifẹ Ọlọrun ni mo bẹrẹ irinajo mi si ori-itẹ. Awọn ahesọ kọọkan wa ti mo fẹẹ ṣe atunṣe si. Mo fẹ ki ẹ mọ pe ki i ṣe tori pe Kabiesi fẹ iyawo miiran ni mo ṣe fẹẹ kuro laafin. Emi nikan ni iyawo lọwọ Ọọni ni gbogbo igba ti mo fi wa lọdọ rẹ, loootọ ni ahesọ wa kaakiri, ṣugbọn ko nitumọ si mi, n ko si gbe e ko o loju ri.

“Lẹyin oṣu diẹ ti a mọra lo dẹnu ifẹ kọ mi. Ko si alarinna kankan laarin wa, yatọ si ahesọ tawọn eeyan kan n sọ pe wolii obinrin kan lo fi wa mọra. Dipo bẹẹ, lẹyin ti a mọra tan ni kabiesi fi mi han obinrin naa.

“Mi o loyun ri laye mi ṣaaju Tadenikawo, ọmọ. Ọmọ mi, Tadenikawo, ni oyun akọkọ ti mo ni ri, akọsilẹ awọn dokita si fidi eyi mulẹ. Ki i ṣe emi ni mo bi ọmọbinrin ti won n pe ni ọmọ mi, ọmọ ẹgbọn mi ni.

“Mo gbiyanju pupọ lati fori ti i, ki nnkan le wa bo ṣe tọ, mo rẹrin-in laarin ipenija nla, ṣugbọn mo ti ri i pe iṣẹ kan ṣoṣo ni mo ni laafin, ohun naa si ni ọmọ mi, nigba ti Ọlọrun si sọ pe o ti tan, o tan naa niyẹn.

“O yan Saulu lati jẹ ọba, nigba to si to asiko lati pari iṣẹ pẹlu ẹ, Ọlọrun sọ fun Woli Samuel pe Oun ti ṣetan pẹlu rẹ. Ọrọ ẹsin ko fa ede-aiyede laarin emi ati Kabiesi. Dipo eleyii, Kabiesi ni awọn aworan ara rẹ to fẹ ki awọn eeyan ri nita, ati eyi to jẹ tiẹ gan-an gan.

“Loni in, mo kede ibẹrẹ ọtun, ati ipari ipele kan. Mo kede pe mo jẹ iya fun ẹbun pataki latọdọ Ọlọrun, ni bayii, ki ẹnikẹni ma ṣe pe mi ni iyawo Ọọni Ifẹ tabi Olori Ileefẹ mọ, bi ko ṣe olori awọn eeyan ati Iya Tadenikawo.

“Mo parọwa si abala mejeeji, nitori Tadenikawo, pe ka faaye gba alaafia Ọlọrun lati jọba.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI