Aláànú mi, olùfọkàntàn ni AbdulRazaq jẹ́ - Ọ̀jọ̀gbọ́n Abubakar Sulaiman - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, February 7, 2022

Aláànú mi, olùfọkàntàn ni AbdulRazaq jẹ́ - Ọ̀jọ̀gbọ́n Abubakar Sulaiman


Alakoso agba fun ile-ẹkọ, Nigerian Institute of Legislative Studies, Ọjọgbọn Abubakar Ọlanrewaju Sulaiman ti sọ ọ sita agbangba wi pe alaanu, oloore ati olufọkantan oun ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara.

Ori ikanni ayelujara ti Fesibuuku ni Ọjọgbọn Abubakar Sulaiman ti sọrọ naa lọjọ Aiku, Sannde ana, to si ni ẹni toun ko le gbagbe titi lai ni Gomina AbdulRazaq jẹ.
 
Ọkunrin naa to tun jẹ alakoso ipolongo idibo fun Ọnọrebu Razak Atunwa ninu idibọ ọdun 2019, to si tun jẹ ọkan pataki lara awọn ọmọlẹyin Sẹnetọ Bukọla Saraki jẹ ko ye gbogbo agbaye wi pe oun pẹlu Gomina AbdulRazaq, ọrẹ bi ọmọ iya lawọn jẹ.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI