Ogun Abẹ́lé: Odindi ìlú kan di ahoro nìpínlẹ̀ Ògùn, lẹ́yin ikú kábíyèsí - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 8, 2022

Ogun Abẹ́lé: Odindi ìlú kan di ahoro nìpínlẹ̀ Ògùn, lẹ́yin ikú kábíyèsí

 
...inu igbo la n sun si, awọn ohun ọsin wa lo n gbe inu ilu bayii – araalu

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
 
Ọrọ wahala to n ṣẹlẹ nilu Agodo, to wa nijọba ibilẹ Ewekoro, ipinlẹ Ogun ko yatọ si ti ogun abẹle tabi ti kiriji lọpọlọpọ ọdun sẹyin, nitori pe gbogbo ilu patapata, to fi mọ baalẹ atawọn olori ilu ni wọn ti sa kuro nibẹ, ti ko si sẹni to le wọnu ilu naa mọ, titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan.
 
AWIKONKO gbọ pe lọjọ kẹrinla, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 ti a wa yii, lawọn kan lọ dena de Ọba Ayinde Ọdetọla, iyẹn ni nnkan bi agogo mọkanla owurọ, ti wọn si luu pa mọ inu mọto ẹ.
 
Lẹyin ti wọn luu pa tan, ṣe la gbọ pe wọn tun dana sun un mọ inu mọto ẹ to jẹ Toyota Venza, eyi to mu ki ariwo ikunlẹ abiyamọ sọ laaarin ilu.
 

Ilu Agodo lo wa ni adojukọ oju ọna to lọ si ilu Ibogun-Ọlaogun, iyẹn nibi ti Aarẹ tẹlẹri lorileede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Okikiọla Ọbasanjọ ti wa.
 
Ninu iwadii AWIKONKO la ti gbọ pe wahala to n ṣẹlẹ yii ti bẹrẹ lati nnkan bi ọdun mẹrin sẹyin, nigba ti wọn sọ pe Ayinde Ọdẹtọla dide lati sọ ara di ọba le wọn lori, lai gba aṣẹ lọwọ awọn agbaagba atawọn oloye to wa nilu.
 
Baba agbalagba, ẹni ọdun mọkandinlaaadọrun kan, Oloye Ajani Ṣotade ni baalẹ ilu naa, to si ti wa lori ipo ọhun lati ọdun 2015, gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe ṣalaye.
 
Wọn ni ilu Ilaro ni Ayinde Ọdẹtọla n gbe tẹlẹ, ko to di pe o de sinu ilu naa ni nnkan bi ọdun mẹrin sẹyin, to si loun fẹẹ jẹ ọba nibẹ. Ere ni wọn lawọn eeyan kọkọ pe e, afi bi ọkunrin naa ṣe bẹrẹ sii da wahala silẹ loriṣirṣi.
 
Mọto ti wọn sun Kabiyesi mọ

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le fidi rẹ mulẹ lakoko yii, a gbọ pe ogbologbo olori awọn ajagungbalẹ ni Ayinde Ọdẹtọla, wọn si ni 
 
Laipẹ yii ni AWIKONKO ṣabẹwọ sinu abule naa, to si jẹ iyalẹnu fun wa nigba ti a ri diẹ lara awọn araalu naa, ti wọn n ko ẹru salọ kuro nilu. Bo tilẹ jẹ pe wọn ko kọkọ fẹẹ sọrọ, ṣugbọn nigba to ya, wọn jẹ ka mọ erongba wọn.
 
Arabinrin Mọrufat Sanyaolu nigba to n sọrọ sọ pe
“Idaamu to ba mi bayii latigba ti ọrọ yii ti ṣẹlẹ ni mo ti n wa ọkọ mi, Abiọdun Sanyaolu. Bi wahala naa ṣe bẹrẹ, inu igbo ni gbogbo wa mu ori le, ibẹ la n sun, ti a n ji lai wẹ. Nigba to to ọjọ kẹrin ti a ti wa ninu igbo, ti ebi n pa wa, lo mu ki ọkọ mi pinnu lati lọ wa ounjẹ fun wa.
 
“Oju ọna lo wa, ti wọn lawọn kan ti jii gbe lọ. Igba to ya ni mo n gbọ pe awọn ọlọpaa lo wa gbe e lọ. Gbogbo teṣan ọlọpaa to wa lagbegbe yii ni mo ti lọ lati beere ọkọ mi, ṣugbọn ti wọn lawọn ko ri ọkọ mi.
 
“Mo n bẹ awọn ọmọ Naijiria lati ṣaanu mi, ki wọn ba mi wa ọkọ mi o. Awọn ọmọ mẹta to da silẹ fun mi ree. Irọlẹ ọjọ Aje, Mọnde to kọja lọhun ni wọn gbe ọkọ mi lọ. Inu igbo la wa, ibẹ la n sun, ti a n ji si, nitori pe ko seeyan nilu mọ.”
 
Ẹyin mọto naa ree

Arabinrin Rọfiat Adeniji, ọkan lara awọn araalu to n ko ẹru salọ ninu ọrọ tirẹ sọ pe 
“Oko la fẹẹ lọ lọjọ naa, ṣa dede la ri ti awọn kan ko ogun wọle pẹlu ibọn atawọn nnkan ija oloro, ti wọn si bẹrẹ sii ba ara wọn ja. Pẹlu ibẹrubojo la fi mu ori wọgbo.
 
“Latigba naa la ti n gbe inu igbo, lonii ti ẹ ri wa yii, awọn ẹru wa yooku la wa ko. A ko fẹẹ pada sinu ilu yii mọ lo jẹ ka wa ko ẹru wa to ku. Ki ijọba ṣaanu wa nilu Agodo, a n fẹ aabo to peye. Wọn ba mọto ọkọ mi jẹ kọja sisọ. Ike nla ti a fi n pọn omi si, ni wọn bajẹ.”
 
Ọgbẹni Salakọ Adewuyi nigba toun naa n sọrọ sọ pe
“Emi naa kan dede ri ina to ṣẹyọ, mo si rii pe awọn eeyan n pariwo, wọn si n salọ. Lai beere ohun to ṣẹlẹ, emi naa darapọ mọ wọn. Ọrọ di ọlọmọ ko mọ ọmọ mọ, ko sẹni to ri oju ẹnikan lasiko yẹn.
 
“Inu igbo la ti n pade ara wa. Ko seeyan kankan laaarin ilu mọ. Nitori ti a gbọ pe awọn akọroyin n bọ lo jẹ ka jade kuro ninu igbo lati wa ba yin, ki ẹ le ba wa sọ fun gbogbo ilu, paapaa ijọba Dapọ Abiọdun lati dide iranlọwọ fun wa.
 
“Ewurẹ, ẹran, adiẹ, atawọn nnkan ọsin wa lo n gbe inu ilu latigba naa. Ebi si n pa gbogbo awọn nnkan ọsin wa, nitori pe awọn gan-an ko ri ounjẹ jẹ.”
 
Baalẹ ilu Agodo

Ọgbẹni Adeniyi Akinjiyan, ẹni to loun ko tii ri awọn mọlẹbi oun latigba naa sọ pe 
“Wahala awọn ajagungbalẹ lo n da wa laamu nilu Agodo. Awọn mẹta lo ti bimọ sinu igbo latigba naa. Iyawo mi atawọn ọmọ mi, latigba naa, mi o le sọ pe ibi ti wọn wa ree, ẹ dakun, ẹ ba mi wa wọn o.
 
“Wọn ni inu igbo ni wọn wa, mo ti wa wọn, ṣugbọn mi o tii ri wọn. Ọmọ temi mẹta, ọmọ-ọmọ mi meji ati iyawo mi meji ni mi o tii ri bi mo ṣe n ba a yin sọrọ yi o. Inu igbo la n sun si bi ẹran bi mo ṣe dagba to yii. Igba miran ti ilu ba ṣu, ori igi ni maa ka jọ si. Mo ti le laadọta ọdun.
 
“Ki ijọba Dapọ Abiọdun, ijọba apapọ ṣaanu wa, nitori pe iṣẹlẹ yii ti n waye, ọjọ ti pẹ. Ẹ gba mi o.”
 
Aafin ti wọn n kọ lọwọ

Oloye Ajani Ṣotade, Baalẹ ilu Agodo ninu ọrọ tirẹ naa sọ pe 
“Mo ji ni nnkan bi agogo mẹjọ aarọ, ni mo n gbọ ti ariwo n lọ lọtun losi, ibi ti mo ti n beere ohun to ṣẹlẹ ni wọn ti sọ pe wọn ti pa ẹnikan, wọn si tun dana sun un mọ inu mọto ẹ. Wọn ni Jide, ati pe Kabiyesi ni.
 
“Mo ṣi ri lọjọ kejilelogun, oṣu to kọja, o ki mi kọja. Awọn janduku ẹgbẹ rẹ lo ṣeku pa. Emi ko mo ẹni ti wọn pa yii gẹgẹ bi kabiyesi, mi o mọ ibi to j’ọba si, gbogbo ilu si le jẹrii sii.
 
“Ko sẹni to le j’ọba lẹyin mi, nitori pe emi ni Baalẹ ilu yii, bi wọn ba si maa yan ọba, emi ni. 2015 ni mo ti wa lori ipo Baalẹ. Lotitọ ọmọ ilu ni, ṣugbọn ilu Ilaro lo n gbe, kii gbe inu ilu yii.
 
“Kani mo ri ọna ni, mi o ba ti salọ, nitori pe ọjọ naa ni gbogbo eeyan ti na papa bora, ko seeyan kankan nilu mọ. A ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un lọ ti n gbe inu ilu yii. Mo fẹ ki ijọba fun wa ni aabo, ki wọn da awọn eeyan mi pada. Ki ijọba paṣẹ pe gbogbo awọn to kuro nilu pada, ati pe ẹni ti ko ba pada, yoo jiya labẹ ofin.
 
“Inu igbo ni emi ti mo jẹ Baale ilu n gbe lasiko yii, ṣe o ṣee gbọ seti. Iranlọwọ ni mo fẹ, ki ijọba da awọn eeyan mi pada silu, ki wọn si pese aabo to pe ye fun wa lai fi akoko ṣofo.”
 
Gbogbo akitiyan lati ba ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọrọ lo ja si pabo titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI