Nítorí ikú Adégòkè, Fálànà ní kí ọ̀gá ọlọ́pàá dá ẹjọ́ padà sí ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 7, 2022

Nítorí ikú Adégòkè, Fálànà ní kí ọ̀gá ọlọ́pàá dá ẹjọ́ padà sí ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun


Gbajugbaja ajafẹtọọ ọmọniyan nni, Amofin Fẹmi Falana, ẹni to tun jẹ agbẹjọro fun mọlẹbi Timothy Oludare Adegoke ti wọn pa danu si otẹẹli Hilton to wa nipinlẹ Ọṣun ti ranṣẹ si ọga ọlọpaa orileede yii, Usman Baba Ahmed lati gbe ẹjọ naa wa si ile-ẹjọ giga t'ipinlẹ Ọṣun, nibi ti igbagbọ wa pe idajọ ododo yoo ti waye.
 
Amofin Falana, ninu lẹta to kọ ranṣẹ si ọga ọlọpaa lọjọ kẹrin, oṣu keji, ọdun ti a wa yii lo ti jẹ ko di mimọ pe ohun ti mọlẹbi Adegoke to gba oun gẹgẹ bi agbẹjọro n fẹ niyẹn. 
 
O sọ siwaju pe niwọn igba to ti jẹ pe ilu Ile-Ifẹ, nipinlẹ Ọṣun ni wọn ti pa Ọgbẹni Timothy Adegoke, wọn ko nilo lati gbe ẹjọ ọhun lọ sibikibi, ati pe ile-ẹjọ to wa lagbegbe naa lo yẹ ki wọn gbe ẹjọ lọ, kii ṣe Abuja.
 
Bẹẹ lo ni ki ọga ọlọpaa da ẹjọ naa pada sipinlẹ Ọsun, lọdọ adajọ agba nipinlẹ ọhun, ki wọn le mọ bi wọn yoo ṣe fẹsun kan afurasi tọwọ tẹ lori iku oloogbẹ naa.
 
O jẹ ko di mimọ pe bi ọga ọlọpaa ba kọ lati tẹle ohun ti wọn n beere, wọn ko ni beṣubẹgba lati pe ileeṣẹ ọlọpaa lẹjọ.
 
 
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI