Dáre Mẹ́lódì àtàwọn akọ̀ròyìn méjì gba mọ́tò bọ̀gìnnì lọ́wọ́ Wòlíì Ayọ̀délé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, February 16, 2022

Dáre Mẹ́lódì àtàwọn akọ̀ròyìn méjì gba mọ́tò bọ̀gìnnì lọ́wọ́ Wòlíì Ayọ̀délé


Ṣe ni idunnu ṣubu lu ayọ gbajugbaja onkọrin nni igbagbọ nni, Dare Mẹlody nigba ti ogbontarigi ojiṣẹ Ọlọrun nni, Wolii Elijah Babatunde Ayọdele gbe mọto bọginni ayọkẹlẹ fun un, lori ipa to n ko lagboole igbagbọ ti Kritẹẹni.

Ẹsẹ ko gbero nibi eto isin idupẹ ti ayẹyẹ ọjọ ibi Wolii Ayọdele, eyi to waye lọjọ ayajọ ololufẹ, iyẹn ọjọ kẹrinla, oṣu ti a wa yii, ọjọ Ajẹ, Mọnde, ijẹta, nilu Eko.
 
Yatọ Dare Mẹlody ti Wolii Ayọdele gbe mọto bọginni fun lọjọ naa, awọn ogbontarigi akọroyin, ti wọn ti wa pẹlu Wolii Ayọdele tipẹ naa gba ẹbun mọto kọọkan gẹgẹ bi ẹmi imoore si wọn.
 

Kii ṣe akọkọ ree ti Wolii Ayọdele, ẹni ti ọpọ awọn asọtẹlẹ rẹ ti wa si imuṣẹ yoo maa fi mọto ta awọn eeyan lọrẹ, ṣugbọn eyi to waye kọja yii kọja ohun afẹnuroyin, gẹgẹ bi aṣe gbọ.
 
Inu ọgba ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church, to jẹ ti Wolii Ayọdele ni eto ayẹyẹ ọhun ti waye, nibi ti ẹsẹ ko ti gba ero. ba alaye, atawọn alẹnulọrọ lawujọ ni wọn wa nibẹ lọjọ naa.

Wolii Ayọdele, nigba to n sọrọ ṣalaye pe boun ṣe maa n fun awọn akọroyin lẹbun mọto lọdọọdun, kii ṣe lati da iṣẹ wọn duro, paapaa nipa iwadii wọn, ṣugbọn lati fi ẹmi imoore han si wọn fun iṣẹ takutakun ti wọn n ṣe lati jẹ ki otitọ farahan lawujọ Naijiria.
 

O ni ọpọ awọn akọroyin lawọn ileeṣẹ ti wọn n ba ṣiṣẹ ko mọ riri wọn, ṣugbọn to jẹ pe wahala wọn lo n gbe ileeṣẹ naa ga, eyi lo sọ pe o jẹ ohun to maa n dun oun lọkan, eyi to jẹ koun pinnu lati maa mọ riri ipa ti wọn n ko.

Lara awọn to wa nibẹ lọjọ naa ni agba nkọrin Juju nni, Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi; Oloye Sunday Adeniyi Adegẹye, tọpọ awọn eeyan mọ si Sunny Ade, ati awọn miran.
 

AWIKONKO gbọ pe Wolii Ayọdele tun fi ẹbun owo ta ọpọ awọn akẹkọọ lọrẹ, to si tun gba fọọmu idanwo JAMB ti ko din ni ẹgbẹrun kan ta awọn akẹkọọ lọrẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI