Onídàájọ Kamaldeen di 'Grand Kadi' fìdíhẹ́ ní Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 17, 2022

Onídàájọ Kamaldeen di 'Grand Kadi' fìdíhẹ́ ní Kwara


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, l'Ọjọru, Wẹisdee to kọja ti bura fun Onidajọ Abdullateef Kamaldeen gẹgẹ bi Grand Kadi tipinlẹ naa, ti ibura yii si waye pẹlu ayẹyẹ nla.
 
AbdulRazaq bura fun Onidajọ Kamaldeen lẹyin ti Grand Kadi ana, Onidajọ Muhammad Ọla AbdulKadir fẹyinti lẹnu iṣẹ, paapaa lẹyin to ti pe ọdun marundinlaadọrin, {65years}.
 
Nigba to n sọrọ, AbdulRazaq sọ pe ipo naa kii ṣe ipo to gbọdọ ṣofo fun ọjọ pipẹ, eyi lo si lo fa a ti wọn fi tete yan ẹlomiran ti yoo dipo naa mu, titi digba ti wọn yoo fi ri ẹni yoo tẹsiwaju iṣẹ.
 
Bakan naa lo gbe oṣuba kare fun Onidajọ Ọla Abdulkadir fun bo ṣe lo ipo ọhun daadaa lai fi ti ọrọ ẹya ṣe, to si ni iru awọn eeyan ti wọn gbọdọ maa tọka si gẹgẹ bi aṣaaju rere ni baba naa.
 
O ni ṣe ni Onidajọ Ọla Abdulkadir tẹle ilana awọn aṣaaju to ti di ipo naa mu, latigba ti wọn da ile-ẹjọ naa silẹ lọdun 1975.
 
Bakan naa lo gba ẹni ti wọn yan gẹgẹ bii Grand Kadi fidihẹ yii lati ma ṣe yẹgẹrẹ kuro ni ilana awọn aṣaaju to ti fipo ọhun silẹ, to si ni ko lo o lati fi mu otitọ ati iṣọkan ba ipinlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI