'Mo rí igi ọ̀pẹ tó wó lu Abacha mọ́lẹ̀ níbi ìpàdé' - Gbajúmọ̀ pásítọ̀ tú àṣírí ikú tó pa Abacha danù - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 7, 2022

'Mo rí igi ọ̀pẹ tó wó lu Abacha mọ́lẹ̀ níbi ìpàdé' - Gbajúmọ̀ pásítọ̀ tú àṣírí ikú tó pa Abacha danù


Aarẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi Salvation Ministries, Pasitọ David Ibiyeomie ti tu aṣiri nla nipa iku to pa olori orileede Naijira lakooko ologun, Ọgagun Sani Abacha lọdun 1998. while in power due to pride.

Pasitọ Ibiyeomie lo tu aṣiri yii lakoko to n waasu nile ijọsin rẹ lọjọ Aiku, Sannde, ana, to si ni 'Igberaga' lo ṣeku pa Abacha lakoko to wa lori iṣakoso.
 
Ọjọ kẹjọ, oṣu kẹfa, ọdun ni Abacha jade laye, ọjọ naa si ni wọn sinku rẹ nilana musulumi.
 
Pasitọ Ibiyeomie, ẹni to sọ pe ṣaaju akoko yii loun ti sọ asọtẹlẹ nipa iku Abacha jẹ ko di mimọ pe ọkunrin naa ni igberaga to kọja sisọ, to si ni ṣe lo gba ipo Ọlọrun, to si fi n gbe ara rẹ ga.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe
“Njẹ ẹ mọ ohun to ṣeku pa Abacha? Ohun to ṣeku pa Abacha ree. Abacha ti figba kan ri jẹ olori orileede Naijiria labẹ ijọba ologun. Mo sọ fun iyawo mi ati awọn kan wi pe Abacha maa ku, ko si to ku ni mo ti sọ eyi. 
 
“Mo sọ fun wọn pe o maa ku. Mo rii wi pe o ku, Sani Abacha. Mo rii wi pe igi ọpẹ wo luu mọlẹ nibi ti wọn ti n ṣe ipade lọwọ. Mo wa sọ pe ọkunrin yii ko ni pẹ ti yoo fi ku. Pupọ ninu yin lẹ ṣi kere, ẹ ko mọ Abacha.
 
“Ọkunrin yii, ki wọn to o ka iroyin alatagba, nigba yẹn, agogo meje owuro ni wọn maa n ka iroyin alatagba, wọn yoo kọkọ kọrin fun un. 'Gbogbo eniyan n jẹri pe Abacha dara, o dara, Abacha o dara, gbogbo eniyan n jẹri pe o dara, o dara, Abacha o dara.'
 
“Orin yii ni wọn yoo kọkọ kọ ki wọn to bẹrẹ sii ka iroyin. Mo sọ pe oku ni ọkunrin yii. Ọlọrun ko le ba ẹnikẹni pin ninu ogo Rẹ. Emi naa si kọrin.
 
“Abacha, nigba ti wọn ba gbe ẹ ni Aso Rock, igba naa lo maa mọ wi pe eeyan buruku ni ẹ. Ni tooto, wọn fi poosi rẹ gbe. Ẹ jọwọ, ẹ yago fun igberaga. Igberaga kii jẹ keeyan mọ ohun to n ṣe.”.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI