Ganduje binu tan: O ni ẹni tọwọ ba tẹ lori iwa ọdaran yoo gba idajọ iku loju ẹsẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 27, 2022

Ganduje binu tan: O ni ẹni tọwọ ba tẹ lori iwa ọdaran yoo gba idajọ iku loju ẹsẹ


Gomina Abdullahi Ganduje, tipinlẹ Kano ti ṣe ikilọ nla fun ẹnikẹni to ba lọwọ si igbebọn, iwa ipaniyan ati pipa maluu nipakupa, to si n ṣeleri wi pe idajọ iku ni yoo tọ si wọn bi ọwọ palaba wọn ba fi segi.
 
Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe fifi ẹran jẹko kaakiri ilu ko ba ti igbalode mu mọ, eyi to ni o fa a ti wọn fi gbe eto RUGA kalẹ, eyi ti yoo fun awọn darandaran lanfaani lati wa ni ojukan, nibi ti wọn yoo ti maa fun maalu wọn lounjẹ, omi ati itọju to peye.
 
Ọjọ Abamẹta, Saitde ana ni Ganduje sọrọ yii nibi ifilọlẹ abẹrẹ ajẹsara fawọn maluu nla ati kekeekee to waye ni Kadawa, ijọba ibilẹ Garun-Mallam.
 
O ni ẹnikẹni tọwọ ba tẹ wi pe o lọwọ si iwa ipaniyan nipakupa, igbebọn, ati ṣiṣe maluu niṣekuṣe yoo gb idajọ iku, lai fi oju aanu wo iru ẹni bẹẹ.
 
Bakan naa lo tun fidi ẹ mulẹ pe ẹni tọwọ ba tẹ wi pe o n fi ẹran jẹko kaakiri yoo lo eyi to ku nigbesi aye ẹ lọgba ẹwọn, nitori pe ẹwọn gbere ni yoo ku si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI