Ọ̀ọ́dúnrún aráàlú wọ gàù lakoko gbálégbáta n'Ílọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, February 27, 2022

Ọ̀ọ́dúnrún aráàlú wọ gàù lakoko gbálégbáta n'Ílọrin


Awọn araalu ti ko din ni ọọdunrun (300) lọwọ awọn agbofinro ti tẹ nipinlẹ Kwara lọjọ Abamẹta tii ṣe Satide to kọja yii, latari bi wọn ṣe tapa si ofin gbalegbata, iyẹn ofin imọtoto ipinlẹ naa.

Iroyin to tẹ wa lọwọ bayii jẹ ko ye wa pe ijọba ipinlẹ naa ti paṣẹ pe ki wọn lọ foju gbogbo wọn ba ile-ẹjọ lai fi akoko ṣofo.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ayika nipinlẹ Kwara, Arabinrin Ọkanlawọn Taiwo fi ranṣẹ si AWIKONKO lonii, ọjọ Aiku, Sannde, o fidi ẹ mulẹ kọmiṣanna f'ọrọ eto ayika, Ọnarebu Abọsẹde Ọlaitan Buraimọh gangan lo rọwọ to awọn eeyan naa kaakiri ilu Ilọrin ati agbegbe rẹ.


Ọkanlawọn tẹsiwaju pe Ọnarebu Buraimọh ti figba kan kilọ fawọn araalu lati yee fi ọwọ yọbọkẹ mu ọrọ eto imọtoto, paapaa eto gbalegbata oloṣooṣu, to si ni gbogbo awọn tọwọ palaba wọn ba segi ni yoo foju winna ofin.

Ọnarebu Buraimọh nigba to n fi ẹdun ọkan rẹ han, o ni iyalẹnu lo jẹ wi pe lẹyin ọpọlọpọ ipolongo, igbaninimọran ti ijọba n ṣe kaakiri, paapaa lori redio ati tẹlifiṣan, awọn eeyan ṣi n tapa si ofin gbalegbata, eyi to lo ku diẹ kaato.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI