Agbẹ bi Jẹbba, telọ, awọn mẹrin miran dero ẹwọn lori ẹsun gbajuẹ n'Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 7, 2022

Agbẹ bi Jẹbba, telọ, awọn mẹrin miran dero ẹwọn lori ẹsun gbajuẹ n'Ilọrin


Onidajọ Muhammed Sani tile ẹjọ giga apapọ to wa ni Ilọrin, ipinlẹ Kwara l'Ọjọbọ ọjọ kẹrin oṣu kẹta, ọdun 2022 sọ awọn mẹfa kan sẹwọn fun ijẹbi ẹsun gbajuẹ ori ẹrọ ayelujara, eyi ti ajọ EFCC ẹka Ilọrin fi kan wọn. 

Awọn eeyan naa ni: Abdulrahaman Ridwan eyi to pe ara rẹ ni agbẹ lati Jebba lagbegbe ijọba ibilẹ Moro ni ipinlẹ Kwara; Yinus Lateef Shọla, telọ lati Omupo, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, ipinlẹ Kwara ati Jimọh Ahmẹd Adeọla lati Ọwọ, nijọba ibilẹ Ọwọ ipinlẹ Ondo. 

Awọn to ku ni, Yinus Muiz Iyanda, Ridwan Ọladimeji lati ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ilọrin ati ẹnikan ti wọn pe ni Gideon Thomas.

Ẹsun ọtọọtọ ni ajọ EFCC fi kan ọkọọkan wọn, eyi ti wọn si gba pe awọn jẹbi rẹ.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI