Ọwọ ọlọpaa ti tẹ awakọ BRT to gbe Oluwabamiṣe lọsẹ to kọja - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 7, 2022

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ awakọ BRT to gbe Oluwabamiṣe lọsẹ to kọja


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fidi rẹ mulẹ wi pe ọwọ awọn ti tẹ awakọ bọọsi ijọba ipinlẹ Eko, eyi ti awọn eeyan tun n pe ni BRT, ẹni ti wọn lo gbe ọdọmọbinrin, ọmọ ọdun mọkanlelogun, Oluwabamiṣe Ayanwọle to dawati.
 
Adekunle Ajiṣebutu to jẹ agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ Eko lo fidi iroyin yii mulẹ lonii, ọjọ Aje, Mọnde, to si ni awakọ naa ti wa lahamọ awọn.
 
Ọjọ kẹrindinlogbọn, oṣu keji, ọdun yii ni Oluwabamiṣe wọ bọọsi BRT, to si jẹ wọn ko mọ bo ṣe rin in latigba naa.
 
Oku Oluwabamiṣe la gbọ pe wọn pada ri lori afara Carter to wa ni Ogogoro, iyẹn lagbegbe Lagos Island, ipinlẹ naa.
 
Ọkan lara awọn amugbalẹgbẹẹ agba fun gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo Olu, Ọgbẹni Jubril Gawat sọ pe oni, ọjọ Aje lọwọ tẹ awakọ naa.
 
Bẹ o ba gbagbe, ileeṣẹ ọlọpaa lọsẹ to kọja rawọ ẹbẹ sawọn araalu lati ta wọn lolobo, iyẹn nibikibi ti wọn ba ti kofiri awakọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI