Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti bu ọwọ lu kikọ ẹka fasiti t'ipinlẹ naa, iyẹn Kwara State University, KWASU s'ijọba ibile Osi ati Ilesha-Baruba.
AWIKONKO gbọ pe ijọba ibilẹ Ekiti, ipinlẹ Kwara ni Osi wa, bakan naa ni Ilesha-Baruba wa n'ijọba ibilẹ Barutẹn, iyẹn nibi ti wọn fẹẹ kọ ẹka fasiti ọhun ti wọn pe ni Satellite Campus si.
Kọmiṣanna to n ri sọrọ ile ẹkọ giga nipinlẹ naa, Senior Ibrahim Sulyman Esq, nigba to n sọrọ fidi rẹ mulẹ wi pe awọn agbaṣẹṣe ti bẹrẹ iṣẹ lakọtun lawọn agbegbe yii.
Sulyman, lakooko to n ṣabẹwo sawọn ibi ti iṣẹ ti n lọ lọwọ lọjọ Ẹti, Furaidee ṣalaye wi pe niwọn igba ti Gomina ti gbe owo silẹ, ko tun si nnkan to n da wọn duro mọ, to si ni ko ni pẹ ti iṣẹ yoo fi pari lawọn ẹka fasiti wọnyii.
No comments:
Post a Comment