Ile-ẹjọ kọ lati gba beeli Adedoyin, nitori iku akẹkọọ fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 7, 2022

Ile-ẹjọ kọ lati gba beeli Adedoyin, nitori iku akẹkọọ fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ


Ile-ẹjọ giga t'ipinlẹ Ọṣun ti kọ lati gba beeli Rahman Adedoyin, alaṣẹ ati oludasilẹ otẹẹli Hilton, nibi ti akẹkọọ Ọbafẹmi Awolọwọ nni, Timothy Adegoke ku si loṣu kọkanla, ọdun to kọja.

 
AWIKONKO gbọ pe ninu idajọ Onidajọ Adepele Ojo to gbọ ẹjọ naa lonii, ọjọ Aje, lo ti sọ pe ko tii si anfaani lati gba beeli rẹ, nitori pe ẹsun ti wọn fi kan an kii ṣe eyi ti wọn le fi ọwọ yẹpẹrẹ mu.
 
Bẹ o ba gbagbe, ṣaaju akoko yii ni agbẹjọro Adedoyin ti rawọ ẹbẹ si ile-ẹjọ naa nipa lẹta, wi pe ki wọn fi aaye silẹ fun ọkunrin naa lati lọ tọju ara rẹ ti ko ya.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI