Ajinde: Gomina AbdulRazaq b'awọn Kristẹni yọ, o tun gba wọn lamọran rere - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, April 17, 2022

Ajinde: Gomina AbdulRazaq b'awọn Kristẹni yọ, o tun gba wọn lamọran rere


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ba gbogbo awọn ọmọlẹyin Jesu Kristi Oluwa wa yọ lori ayẹyẹ ọdun Ajinde to wọle wẹrẹ yii, to si ni ki wọn maa ranti ọjọ naa si rere.

AbdulRazaq sọ pe asiko yii jẹ akoko ikora-ẹni-ni-ijanu, akojọpọ ifẹ, irubọ, idariji ni ati ifarajin fun Ọlọrun fun gbogbo awọn ọmọlẹyin Jesu Kristi, ati gbogbo eeyan lagbaye.

Ninu atẹjade ti Gomina AbdulRazaq gbe kade lopin ọsẹ to ṣẹṣẹ pari yii lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye lo ti gba awọn eeyan lamọran lati lo anfaani akoko yii sunmọ Ọlọrun, Ẹlẹda wọn.

Bakan naa lo gba awọn ọmọ Naijiria naa lamọran lati fi asiko yii wa ojurere Ọlọrun fun orileede yii, ki wọn si f'imọ ṣ'ọkan lodi si awọn iwa buburu, eyi ti wọn fẹẹ fi tu orileede yii kan, ati lati gbogun ti awọn eniyan inu rẹ nipa iwa ipa ati didori eto ọrọ aje kodo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI