Ẹ gba mi lọwọ Barry-Showkey o - Saheed Oṣupa pariwo sita l'Amẹrika - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, April 17, 2022

Ẹ gba mi lọwọ Barry-Showkey o - Saheed Oṣupa pariwo sita l'Amẹrika


Asiko ti a wa yii ko fi bẹẹ dun mọ gbajugbaja onkọrin Fuji nni, Alaaji Akorede Babatunde Okunọla, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Saheed Oṣupa ninu rara, lori bo ṣe fi ẹsun kan Ọgbẹni Balogun Adewale Akanji, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Barry-Showkey wi pe o n dina atijẹ oun l'Amẹrika.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, lati bi ọsẹ meloo kan sẹyin ni wọn sọ pe Saheed Oṣupa, iyẹn Ọba Orin ti wa lorileede Amẹrika, nibi to ti lọ ṣere fun gbogbo awọn ololufẹ rẹ nibẹ.

Wọn ni gbara ti Saheed Oṣupa ti de si Amẹrika, lo ti fi ara rẹ han fun gbogbo awọn alatilẹyin rẹ nibẹ, ki wọn le gbe iṣẹ orin kikọ lati da wọn laraya fun un.

Lara awọn agba onkọrin Fuji to tun wa l'Amẹrika lati lọ ṣere ni Aarẹ Shina Akanni tọpọ tun mọ si Aroworeyin tabi Ọgọlorin-wa, ẹni ti wọn lo ti ṣaaju Oṣupa de s'Amẹrika.

Wọn ni manija Oṣupa to wa l'Amẹrika, iyẹn Wale lo n ba ọkunrin naa wa ode ere ti yoo ti kọrin fawọn ololufẹ orin Fuji, ti a si gbọ pe manija Aroworeyin naa ti wọn n pe ni Bọbby naa n ba ọkunrin naa gba ode ere.

Ṣadede ni wọn l'Oṣupa ko fi bẹẹ ri ode ere lọ daadaa bii igba to ṣẹṣẹ de s'Amẹrika mọ, ti wọn si ni Aarẹ Aroworeyin ko figba kan ma lọ si ode ere.

Ninu iroyin to tẹ wa lọwọ laipẹ yii ni wọn ti sọ pe Saheed Oṣupa ti n f'ẹsun kan Barry-Showkey, ọkan lara awọn ọmọ agba olorin to ti f'ilẹ ṣ'aṣọbora, iyẹn Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister wi pe oun lo wa nidi b'oun ko ṣe ri iṣẹ orin gba.

Wọn lo sọ pe Aroworeyin nikan lo n ba gba iṣẹ to yẹ koun gba, eyi ti wọn lo sọ pe ko bojumu to.

Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i le f'idi otitọ mulẹ, wọn ni ṣe ni Oṣupa f'oju pa Barry-Showkey rẹ nigba to de s'Amẹrika, eyi lo fa a tiyẹn ko fi ri ti ẹ ro, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Wọn ni ariwo ti Oṣupa n pa kaakiri Amẹrika to wa bayii ni pe Aroworeyin nikan lo n mu kaakiri ode ere, ti ko si jẹ koun ri iṣẹ orin gba, eyi to ni iwa naa ko dara rara.

Gbogbo akitiyan lati ba Saheed Oṣupa sọrọ, ko le f'idi rẹ mulẹ fun wa lo ja si pabo, koda ti a tun gbiyanju lati ba Wale to jẹ manija Oṣupa sọrọ, ṣugbọn tiyẹn loun yoo ba wa sọrọ laipẹ, to si ṣeni laanu pe titi di akoko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan la ko ti i gbọ nnkankan lati ọdọ rẹ.

Bakan naa la ba Akanji Barry-Showkey, ọmọ Agbajelọla sọrọ lori iṣẹlẹ yii, to si jẹ ko ye pe ẹẹkan ṣoṣo loun pẹlu Saheed Oṣupa f'oju kanra latigba to ti de s'Amẹrika.

Ọkunrin naa jẹ ko di mimọ pe ẹni to ba ri oun nikan loun maa n ri, fun idi eyi, o loun ko mọ nnkankan nipa ode ere ti Shina Akanni n lọ, bo tilẹ jẹ pe oun naa maa n de ibi to ba ti n kọrin lati gbafẹ.

Nigba toun naa n b'AWIKONKO sọrọ, Alaaji Akanni sọ pe ko si otitọ nibẹ wi pe Barry-Showkey lo n ba oun gba ere toun n lọ, ati pe ẹẹkan ṣoṣo pere loun pẹlu Saheed Oṣupa f'oju kanra nigba toun fi wa l'Amẹrika ko to di pe oun de pada si Naijiria lọjọ diẹ sẹyin.

Aroworeyin sọ pe koun to o kuro ni Naijiria lọ s'Amẹrika loun ti mọ gbogbo ibi toun yoo ti ṣere, eyi lo jẹ ko rọrun foun lati tete pada sile nigba toun ṣetan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI