Wahala de! Idaamu tuntun tun de ba Tọpẹ Alabi lori ẹsun jibiti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, April 17, 2022

Wahala de! Idaamu tuntun tun de ba Tọpẹ Alabi lori ẹsun jibiti


Pẹlu bi nnkn ṣe n lọ yii, afaimọ ni ki gbajugbaja olorin ẹmi nni, Arabinrin Tọpẹ Alabi ma pada foju ba ile-ẹjọ lori ẹsun jibiti, bo tilẹ jẹ pe iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ọkan obinrin naa ko balẹ rara lakoko yii.
 
Awọn orin mẹta kan to wa ninu awo orin 'Angẹli Mi' ti Tọpẹ, ọkọ Sọji Alabi kọ lọdun diẹ sẹyin ni iroyin fi to wa leti pe obinrin naa lu jibiti rẹ lẹyin to ti ta a fun baba olowo kan.
 
Wọn ni orin 'Angẹli Mi', 'Jesu Olurapada' ati 'E Gbe Ga', to wa ninu awo orin 'Angẹli Mi' eyi ti ileeṣẹ NPC Records, Audioworks Limited to jẹ ti gbajugbaja puromota kan l'Amẹrika, Alaaji Tajudeen Bioku gbe jade ni wọn sọ pe Tọpẹ lu jibiti rẹ pẹlu bo ṣe ta a fun ileeṣẹ ikansira-ẹni mẹta ọtọọtọ lati maa fi pawo.

AWIKONKO gbọ pe ọdun 2006 ni Tọpẹ Alabi ati Alaaji Bioku tọwọ bọwe adehun lori awo orin yii wi pe obinrin naa ko nii laṣẹ lori awo orin naa mọ, lẹyin to ti ta a danu. 
 
Wọn ni adehun ti Tọpẹ ṣe fun Alaaji naa ni pe oun yoo ṣe awọn orin naa lede Yoruba ati Oyinbo, ti wọn si ni ọkunrin naa san owo nla fun un.
 
A gbọ pe ọdun 2011 ni aṣiri nla kan tu si Alaaji Bioku lọwọ pe Tọpẹ Alabi ti ta awọn orin naa fun ileeṣẹ MTN, AIRTEL ati GLO lati maa fi pawo wọle s'apo wọn, ko da, ọdun mẹwaa la gbọ pe adehun to tọwọ bọ pẹlu wọn.
 

Ẹwẹ, AWIKONKO gbọ pe Alaaji Bioku ti gbe awọn ileeṣẹ mẹtẹẹta yii lọ sile-ẹjọ giga tiluu Ikoyi lori ẹsun jibiti, to si n beere fun miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta naira lọwọ ileeṣẹ kọọkan gẹgẹ bi owo 'gba ma binu'.
 
Ninu iwe ẹsun naa la gbọ pe ọkunrin yii ti sọ pe Tọpẹ ko lẹtọ s'awọn orin to ta fun wọn yii, nitori pe oun ti ra a lọwọ ẹ, to si di di t'oun.

Lati f'idi iroyin yii mulẹ, a gbiyanju lati fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si Tọpẹ Alabi lori foonu rẹ, iyẹn l'ọsẹ to kọja yii, ti ko si da esi atẹjiṣẹ naa pada titi ti a fi pari akojọpọ iroyin yii.

Bakan la rii gbọ pe ẹmẹta ọtọọtọ ni Alaaji Bioku ti kọ iwe s'awọn ileeṣẹ ikansira-ẹni yii lati ye e lo awọn orin naa mọ, ṣugbọn ti wọn ko dahun, eyi lo jẹ ko pe wọn lẹjọ lori ẹ, to si n beere fun owo gba ma binu lọwọ wọn.

Bẹẹ, a gbọ pe inu oṣu kẹfa, ọdun 2022 yii ni Tọpẹ Alabi, ileeṣẹ MTN, AIRTEL ati GLO yoo f'oju ba ile-ẹjọ lati wa ṣalaye ohun ti wọn ri l'ọbẹ ti wọn fi gaaru ọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI