Amaechi wọ ìpínlẹ̀ Kwara, ó ṣàbẹ̀wò sí Ẹmir ìlú Ìlọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 22, 2022

Amaechi wọ ìpínlẹ̀ Kwara, ó ṣàbẹ̀wò sí Ẹmir ìlú Ìlọrin


Minisita tẹlẹri fun ọrọ igbokegbodo ọkọ lorileede Naijiria, Ọnarebu Chibuike Rotimi Amaechi lopin ọsẹ to ṣẹṣẹ n pari yii ti ṣe abẹwo silu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ni ipalẹmọ fun idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC to n bọ lọna laipẹ.

Rotimi Amaechi, ẹni toun naa n foju sọna lati dije du ipo aarẹ orileede yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC lọ ṣe abẹwo oṣelu si Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara at'awọn oloye ẹgbẹ naa fun imurasilẹ eto idibo abẹle.

Nibẹ lo ti jẹ ki wọn mọ erongba rẹ lati dije du ipo aarẹ, ati awọn ipinnu rẹ fun gbogbo ọmọ Naijiria lapapọ.

Ninu abẹwo yii lo tun ti ya ni aafin Ẹmir tilu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari lati wolẹ fun ori ade.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI