'Bulldozer' di alága ìgbìmọ̀ ìṣàkóso ilé-ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ti Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 22, 2022

'Bulldozer' di alága ìgbìmọ̀ ìṣàkóso ilé-ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ti Kwara


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti bu ọwọ lu aṣoju-ṣofin tẹlẹ ri nilu Abuja, Ọnatebu Yahaya Ahmed Yinusa, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Bulldozer gẹgẹ bi alaga igbimọ iṣakoso ile-ẹkọ fbogboniṣe ti ipinlẹ Kwara.

Bakan naa ni AbdulRazaq tun yan Onimọ-ẹrọ Yaru Swanru Salihu (PhD) gẹgẹ bi ọga agba fun ile-ẹkọ International Vocational, Technical and Entrepreneurship College (IVTEC), to aa niluu Ajaṣẹ-Ipo, ipinlẹ naa.

Ọnarebu Yinusa, to ṣoju agbegbe kan nipinlẹ Kwara niluu Abuja laaarin ọdun 1999 si 2007 ni wọn yan lati rọpo Ọmọwe Yaru toun kọwe fipo silẹ lati di ọga agba IVTEC.

AWIKONKO gbọ pe Ọnarebu Yinusa kawe pupọ, to si ni imọ kikun nipa eto ẹkọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI