Mi o ni fi oṣelu silẹ bi mi o ba di aarẹ Naijiria - Tinubu ṣeleri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 18, 2022

Mi o ni fi oṣelu silẹ bi mi o ba di aarẹ Naijiria - Tinubu ṣeleri


Oludije sipo Aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ti sọ pe oun ko ni fẹyinti nidii oṣelu ayafi boun ba di aarẹ orileede yii, gẹgẹ bo ti wa lọkan oun lati sin gbogbo ọmọ ilẹ yii lapapọ.
 
Aṣiwaju Tinubu, ẹni to tun jẹ aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu naa lo sọ eyi di mimọ laipẹ yii lakoko to gbe ipolongo rẹ lọ s'ipinlẹ Benue, nibi to ti lọ fi erongba rẹ han s'awọn ọmọ ipinlẹ ọhun.
 
O ni bi oun ba fi le di aarẹ orileede yii, gbogbo awọn ọgbọn oun nidii oṣelu, paapaa gẹgẹ bi gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Eko loun yoo lo lati fi mu idagbasoke to lọọrin ba ilẹ Naijiria.

Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe oun nikan lẹni to yẹ fun ipo aarẹ, ati pe ko si ifigagbaga kan ti yoo mi oun titi, iyẹn bi ẹgbẹ oṣelu APC ba fa oun kalẹ gẹgẹ bi adije wọn, to si loun yoo bori ẹnikẹni ti ẹgbẹ oṣelu PDP ba fa kalẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI