Gomina ana n'ipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun ati Gomina Dapọ Abiọdun to n ṣakoso lọwọlọwọ ti ba gbogbo awọn ọmọlẹyin Anọbi kaakiri agbaye, paapaa nipinlẹ Ogun yọ fun ti ayẹyẹ ọdun ipari aawẹ Ramadaani to wọle wẹrẹ.
Sẹnetọ Ibikunle Amosun, ẹni to n ṣoju Aarin Gbungbun ipinlẹ Ogun nile igbimọ aṣofin agba l'Abuja ninu ọrọ ikini rẹ gbadura pe ki ibukun Allah kun inu aye gbogbo eeyan pẹlu idunnu ati pe ki ilẹkun aṣeyọri ṣi fun wọn lakoko yii ati titilai.
No comments:
Post a Comment