Lẹ́yìn tó pàdánù ipò ààrẹ s'ọ́wọ́ Tinubu, wọ́n ní Ọ̀ṣínbàjò ti gba gbogbo owó tó ná padà lọ́wọ́ àwọn 'Dẹ́lígèètì' ní Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 24, 2022

Lẹ́yìn tó pàdánù ipò ààrẹ s'ọ́wọ́ Tinubu, wọ́n ní Ọ̀ṣínbàjò ti gba gbogbo owó tó ná padà lọ́wọ́ àwọn 'Dẹ́lígèètì' ní Kwara


Bo tilẹ jẹ pe a ko le f'idi rẹ mulẹ daadaa, ṣugbọn iroyin to tẹ wa lọwọ ti fi ye wa pe igbakeji aarẹ orileede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ti gba gbogbo owo to gbe silẹ f'awọn aṣoju oṣelu ti wọn lọ dibo nibi idibo abẹlẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC fun ipo aarẹ to waye kọja yii pada.
 
Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo lo jade lati du ipo aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, ṣugbọn to padanu s'ọwọ Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu.
 
Ipo kẹta ni Ọṣinbajo ṣe ninu awọn oludije ti wọn jade du ipo ọhun.
 
AWIKONKO gbọ pe ipinlẹ Kwara nikan ni wọn di gbogbo ibo wọn fun Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu,, gẹgẹ bi esi ibo to jade ṣe sọ.
 
Wọn ni ẹyin Tinubu ni gbogbo awọn aṣoju oṣelu ti a mọ si dẹligeeti, iyẹn 'Delegates' n'ipinlẹ Kwara wa patapata.
 
Ṣaaju ọjọ idibo abẹle la gbọ pe Ọṣinbajo lọ b'awọn aṣoju ti wọn yoo dibo lati Kwara, to si gbe owo kalẹ fun wọn lati le dibo fun un, ṣugbọn to jẹ pe ileri ori ahọn ni wọn ṣe fun un.
 
Lẹyin ti esi idibo ọhun jade, lo ṣẹṣẹ fi oju han sita wi pe ko si ẹnikan ṣoṣo lati ipinlẹ Kwara to dibo fun Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Yinubu ni gbogbo wọn ṣiṣẹ fun.
 
Pẹlu ibinu la gbọ pe Ọṣinbajo fi ran ọkan lara awọn ọmọ ẹyin rẹ, Onimọ-ẹrọ Tobi lati lọ fi awọn agbofinro dunkoko mọ gbogbo awọn aṣoju to gba owo naa, ti wọn ko si dibo, lati da owo pada.

Bayii ni esi idibo naa ṣe lọ si

South-West: 
Lagos – 60 BAT - 55
Ekiti – 48 BAT - 05
Ogun – 60 BAT - 30
Osun – 90 BAT - 80
Oyo – 99 BAT - 85
Ondo – 54 BAT - 43
Total = 411 Total = 298

South-South: 
Akwa Ibom – 93 BAT - 10
Bayelsa – 24 BAT - 10
Cross River - 54 BAT - 10
Delta – 75 BAT - 30
Edo – 54 BAT - 38
Rivers – 69 BAT - 01
Total = 369 Total = 99

South-East: 
Abia – 54 BAT - 01
Anambra – 63 BAT - 01
Enugu – 51 BAT - 05
Ebonyi – 39 BAT - 01
Imo – 81 BAT - 02
Total = 288 Total = 10

North-East: 
Adamawa – 63 BAT - 40
Bauchi – 60 BAT - 49
Gombe – 33 BAT - 25
Borno – 81 BAT - 74
Yobe – 51 BAT - 05
Taraba – 48 BAT - 30
Total = 336 BAT = 223

North-Central: 
Kogi – 63 BAT - 00
Kwara – 48 BAT - 48
Benue – 69 BAT - 55
Plateau – 51 BAT - 23
Nasarawa – 39 BAT - 30
Niger – 75 BAT - 62
FCT Abuja – 18 BAT - 06
Total = 363 Total = 224

North-West: 
Kaduna – 69 BAT - 40
Kano – 132 BAT - 120
Katsina – 102 BAT - 91
Kebbi – 63 BAT - 52
Jigawa – 81 BAT - 40
Sokoto – 69 BAT - 50
Zamfara – 42 BAT - 24
Total = 558 Total= 417

Grand Total =2,340   
BAT Total = 1,271.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI