Gbogbo akẹkọọ lo lẹtọọ lati wọ Ijaabu lọ sileewe - Ijọba Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 6, 2022

Gbogbo akẹkọọ lo lẹtọọ lati wọ Ijaabu lọ sileewe - Ijọba Kwara


Bi jọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe paṣẹ wi pe ki wọn pada ṣilẹkun ile-ẹkọ itẹbọmi ti Oyun, bakan naa ni wọn tun kede sita pe gbogbo awọn akẹkọọ to ba nifẹẹ si i lo lẹtọọ lati wọ aṣọ ibori awọn musulumi ti a mọ si Ijaabu.
 
Ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ eto ẹkọ ati idagbasoke ọmọniyan, Ministry of Education and Human Capital Development n'ipinlẹ naa lo kede ṣiṣi ile-ẹkọ naa pada l'ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii.

Ninu atẹjade ti akọwe agba ileeṣẹ naa, Arabinrin Mary Kẹmi Adeọṣun fi sita, o ni ijọba ti paṣẹ pe ki gbogbo olukọ ati akẹkọọ pada s'ẹnu iṣẹ ati ẹkọ wọn, ko to digba ti eto yoo pari patapata.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI