Ko si ijọba ibilẹ ti ko jẹ anfaani Gomina AbdulRazaq n'ipinlẹ Kwara - Awọn ọba alaye sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 26, 2022

Ko si ijọba ibilẹ ti ko jẹ anfaani Gomina AbdulRazaq n'ipinlẹ Kwara - Awọn ọba alaye sọrọ


Gbogbo awọn ọba alaye ti wọn wa ni ẹkun Ariwa ipinlẹ Kwara ni wọn l'awọn ti fi ontẹ lu saa keji fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, lori awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke to n ṣe lati ọdun mẹta le diẹ sẹyin.
 
Awọn ọba alaye naa sọ pe ko si ijọba ibilẹ ọhun ati agbegbe to fi mọ igberiko kaakiri ipinlẹ ọhun ti wọn ko jẹ anfaani gomina naa nipa iṣẹ idagbasoke to dawọ le.
 
Nibẹ naa ni wọn tun ti jẹ ko di mimọ pe ọpọ awọn anfaani l'awọn to wa lati ẹkun Ariwa naa ti jẹ, eyi ti awọn ko lero rẹ tẹlẹri.

Ọrọ yii lo jade nibi eto akanṣe adura fun baba abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Alaaji Salihu Aliyu Gwanara to jade laye laipẹ yii, eyi ti wọn ṣe n'ijọba ibilẹ Gwanara Baruten.

"Gbogbo awa ti a wa n'ijọba ibilẹ Ariwa Kwara la jẹ ọpọlọpọ anfaani ijọba yii. Mo tun ranti igba akọkọ ti mo wa si Gwanara, ṣugbọn lonii, itan naa lati Ilesha Maruba titi de Gwanara lo ti yi pada gidi. Irin ajo naa ko jinna mọ bi i ti igba kan." - Etsu Patigi, Alaaji Ibrahim Umar, Bologi keji, to tun jẹ olori awọn ọba alaye l'Ariwa Kwara.
 
"Asiko ibanujẹ la wa yii, ṣugbọn a ni ọpọ ohun rere lati sọ nipa iṣakoso yii. Bo tilẹ jẹ pe asiko ọhọngogo la wa yii, sibẹ iṣakoso yii n gbiyanju lati ri i pe gbogbo agbegbe ati igberiko ni wọn mọ riri ijọba. Iṣakoso yii n gbiyanju lati yi aye awọn araalu pada si rere"
 
Ẹmir t'ilu Gwanara, Alaaji Sabi Idris naa gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRazaq lori awọn iṣẹ rẹ, to si l'oun ko lero pe ayipada rere to de ba ipinlẹ naa le waye, ati pe ṣe ni iṣakoso yii mu awọn kuro ninu okunkun bọ sinu imọlẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI