Ẹ fọkanbalẹ o, eto aabo to peye ti wa - Ijọba Kwara f'ọkan awọn araalu Aiyegunlẹ balẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 6, 2022

Ẹ fọkanbalẹ o, eto aabo to peye ti wa - Ijọba Kwara f'ọkan awọn araalu Aiyegunlẹ balẹ


L'ọjọ Aiku, Sannde ana n'ijọba ipinlẹ Kwara fi ọkan gbogbo awọn ara ati olugbe ipinlẹ naa, paapaa awọn olugbe ilu Obbo Aiyegunle balẹ lori iṣẹlẹ ikọlu to waye laipẹ yii.

Agbegbe naa la gbọ pe wọn ti ji awọn kan gbe, ti wọn si tun pa eeyan meji laipẹ yii, bi ẹ ko ba gbagbe.
 
Ijọba Kwara ti wa rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn eeyan lati ma ṣe ko ọkan wọn soke mọ, ki wọn si f'ọkan balẹ nitori pe eto aabo to peye ti wa nibẹ, nipa bi wọn ṣe da awọn oṣiṣẹ eleto aabo sibẹ.
 
Wọn ni awọn ọlọpaa, oṣiṣẹ ologun at'awọn ileeṣẹ eleto aabo miran ni wọn ti dari lọ sibẹ lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu.
 
Bakan naa ni ijọba tun ba awọn mọlẹbi eeyan meji ti awọn agbebọn ṣeku pa kẹdun, ti wọn si lawọn yoo ṣe iwadii lati rọwọ to awọn ọdaran to ṣiṣẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI