Ilu-mọ-ọn-ka pedepede, Idowu Taiwo di aṣoju ileeṣẹ ‘IDGE MERIT PROPERTIES’ to n ṣowo ilẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 20, 2022

Ilu-mọ-ọn-ka pedepede, Idowu Taiwo di aṣoju ileeṣẹ ‘IDGE MERIT PROPERTIES’ to n ṣowo ilẹ


Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Orin ọpẹ l’awọn ololufẹ gbajugbaja pedepede nni, Idowu Taiwo ti ọpọ awọn eeyan mọ si Ọdẹ Apẹran mu s’ẹnu l’ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii nigba ti wọn ṣe e l’ẹṣọ gẹgẹ bi aṣoju ileeṣẹ nla to n ṣowo ilẹ ati dukia kaakiri orileede Naijiria.

Ileeṣẹ naa, IDGE MERIT PROPERTIES & INVESTMENT LTD la gbọ pe wọn fi ipo naa da Ọdẹ Apẹran, ti pupọ awọn eeyan tun n pe ni 'Baba Ayọ Triple', latari awọn ipa to n ko lagboole pedepede, ati paapaa idagbasoke ileeṣẹ naa.

Gbọngan ayẹyẹ ile itura ti Laleck to lagbegbe Logbara, ilu Orile-Imọ, opopona maroṣe Abẹokuta si Ṣagamu, ipinlẹ Ogun ni eto ọhun ti waye, nibẹ si la gbọ pe wọn ti fi ileeṣẹ naa lelẹ.


Ara, ọrẹ, alabaṣiṣẹpọ, ojulumọ, iyawo, awọn ọmọ to fi mọ gbogbo awọn afẹnifẹre ni wọn inu gbọngan ayẹyẹ naa fọnfọn lati ba Ọdẹ Apẹran yọ ayọ ti oriire tuntun naa.
 
Nigba to n sọrọ nipa ileeṣẹ naa, ati idi ti wọn fi yan Idowu Taiwo gẹgẹ bi aṣoju ileeṣẹ wọn, Amofin Tajudeen Olufẹmi Idris, alaṣẹ ati oludari sọ pe, bo tilẹ jẹ pe o ti pẹ t’oun ti wa lẹnu iṣẹ tita ile ati ilẹ gẹgẹ ni Amofin, ṣugbọn to l’awọn bẹrẹ labẹ ofin l’ọdun meji sẹyin.

“Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2020 la fi orukọ ileeṣẹ yii silẹ labẹ ajọ iforukọsilẹ ileeṣẹ lorileede yii, iyẹn Corporate Affairs Commission. Ilu Abẹokuta ni olu ileeṣẹ wa wa, bẹẹ la si ni ẹka si gbogbo ipinlẹ to wa kaakiri ilẹ Yoruba. Nipa oore ọfẹ Ọlọrun, a tun ṣi maa ni ẹka kaakiri orileede Naijiria laipẹ.

“Mo ti wa nidi iṣẹ Amofin, o ti le l’ọdun mẹtadinlogun, mo si ti gbẹjọro lori ọrọ to ni i ṣe pẹlu ija ilẹ ayi ile, ti Ọlọrun si n mu mi bori wọn. Awọn onibara mi yii ni wọn n sọ pe ki n maa ba wọn ta ilẹ wọn nigba ti wọn ba gba idajọ ile-ẹjọ. Igba ti mo ri i pe ki i ṣe nnkan kekere, lo jẹ ki n pinnu lati fi tita awọn ilẹ naa sabẹ ileeṣẹ kan, eyi lo jẹ ki n pinnu lati fi orukọ ileeṣẹ naa silẹ.


“O ti le l’ọdun mẹwaa ti mo ti n ba wọn ta ilẹ bayii nigba ti a ba bori ẹjọ nipa wahala ilẹ. Mi o kan fẹ maa ta ilẹ lasan, lo jẹ ki n pinnu lati da ileeṣẹ to n ṣ’owo ilẹ. Gẹgẹ bi Amofin, ọpọlọpọ igbesẹ ni mo gbe lati ri i pe ileeṣẹ mi yatọ si awọn ileeṣẹ to ku ti a jọ n ṣowo ilẹ labẹ ofin. Oriṣiriṣi ẹsun la ti gbọ ti wọn ti fi kan ọpọ ileeṣẹ bi i ti wa yii, ṣugbọn awa ti ṣe awọn iṣẹ amurele wa daadaa, ko to di pe a jade sita, ki a le da yatọ laaarin awọn akẹgbẹ wa.

“A fi n da awọn onibara wa loju wi pe ko si wahala kankan lori awọn ilẹ ti wa, nitori pe gbogbo iwe aṣẹ ati ẹri la ni lori gbogbo awọn ilẹ to wa labẹ ileeṣẹ wa, wọn ko si ni kabamọ wi pe wọn wa ra ilẹ l’ọdọ wa, ati pe gẹgẹ bi amofin, mo mọ awọn ohun to tọ mọ ọrọ ilẹ.”

Bakan naa nigba to n sọrọ lori idi pataki ti wọn fi yan ogbontagi sọrọsọrọ ati adẹrinpoṣonu nni, Idowu Taiwo,Ọdẹ Apẹran gẹgẹ bi aṣoju ileeṣẹ wọn, o ni oun mọ iru eeyan ti ọkunrin naa jẹ, ati awọn ipa to ti ko, eyi lo fa a ti igbimọ ileeṣẹ naa ṣe fi ẹnu ko lati yan an.

“A ni ọpọ awọn ileeṣẹ bi i ti wa, to jẹ pe awọn oṣere tiata ni wọn fi n ṣe aṣoju wọn, ṣugbọn awa pinnu lati ṣe ti wa lara-ọtọ. Yatọ si eyi, a ni lati yan ẹnikan to gbajumọ daadaa, ti awọn eeyan si nifẹẹ. O ti to ọdun meje bayii ti mo ti mọ Idowu Taiwo, bo tilẹ jẹ pe a ko ti i f’oju kan ara ri.

“Mo mọ pe agba sọrọsọrọ ni, to si tun jẹ akọroyin to dantọ. Mo ti tẹti si ọpọ awọn eto rẹ lori redio ati lori itage. A wa pinnu lati ṣe ohun ara-ọtọ to yatọ si awọn yooku, mo si nigbagbọ pe nipa rẹ, a maa ri ipa rere lati ara rẹ. Ọpọ awọn ileeṣẹ to n ta ilẹ ati ile ni wọn ki i lo akọroyin ati sọrọsọrọ gẹgẹ bi aṣoju wọn, ṣugbọn awa ko fẹẹ tẹle ti wọn, lo jẹ ka ṣe bẹẹ.”


Ninu ọrọ tiẹ naa, Idowu Taiwo sọ pe idunnu nla lo jẹ f’oun nigba ti wọn mu iwe wa wi pe oun ni wọn fẹẹ lo gẹgẹ bi aṣoju ileeṣẹ naa, nitori pe oore nla t’oun ko la ala rẹ ri tẹlẹ ni, ati pe lara awọn ipa t’oun n ko lagboole sọrọsọrọ ati akọroyin lo fa a ti wọn fi wo o pe oun l’ẹni ti ipo naa tọ si.

“O dun mọ mi ninu lọpọlọpọ nitori pe ohun ti mi o lero rẹ tẹlẹ ni. Ninu iṣẹ teeyan ba n ṣe, ti ko ba fi silẹ, yoo ṣe rere nibẹ, apẹẹrẹ rẹ si ree. Beeyan ba gun ẹṣin ninu mi lakoko yii, iru ẹni bẹẹ ko ni i kọsẹ rara, tori pe ohun ayọ ni. Ọlọrun si ni ọpakutẹlẹ ohun gbogbo ti mo n ṣe nitori Oun ni mo fi n ṣiwaju lojoojumọ.

“Ẹni to jẹ alakoso ileeṣẹ yii jẹ amofin, agbẹjọro ni wọn jẹ. O si da mi loju pe ẹni to ba mọ ofin ki i rufin, lo jẹ ki n gba ipo ti wọ fun mi. Mo mọ pe wọn ko le lu jibiti, nitori ti wọn mọ atubọtan to wa nidii ka maa lu jibiti, eyi lo jẹ ki ọkan mi balẹ.

“Gbogbo ohun to rọ mọ ofin ka ra ilẹ, ka ta ilẹ ati dukia lai lu jibiti ni wọn mọ. Pupọ awọn nnkan ti mo si n ri i pe wọn n ṣe ni wọn n ṣe pẹlu ofin, eyi gan-an lo fun mi ni oore ọfẹ lati ba wọn ṣiṣẹ papọ gẹgẹ bi aṣoju wọn.”







No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI