AbdulRazaq ṣabẹwo ibanikẹdun si Alanamu t'iluu Ilọrin lori ọja to jona - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 26, 2022

AbdulRazaq ṣabẹwo ibanikẹdun si Alanamu t'iluu Ilọrin lori ọja to jona


L'ọjọ Aje, Mọnde ana ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe abẹwo si Alanamu t'iluu Ilọrin, Ọba Usman Abubakar Jos lati ba wọn kẹdun lori ọja Alanamu to jona, to si fi ọpọ dukia olowo iyebiye ṣofo danu, t'awọn meji si padanu ẹmi wọn.

Alẹ ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii ni iroyin fi ye wa pe ọja naa jona, ṣugbọn ti awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana gbiyanju agbara wọn.

Nini abẹwo ọhun ni Gomina AbdulRazaq ti ṣeleri wi pe oun yoo dide iranlọwọ fawọn to padanu dukia ati ọja wọn.

Bakan naa ni gomina tun ṣe abẹwo si Balogun Alanamu lori iku iyawo rẹ, Hajia Saadah Iyabọ ti awọn eeyan mọ si Iya Koko, ati amugbalẹgbẹẹ rẹ kan Alaaji Sa'adudeen Alagola ti wọn tun n pe ni Malimu.

O wa gbe oriyin fun awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana lori bi wọn ṣe tete dide si ijamba ina naa, to si ni ileeṣẹ to n ri sọrọ iṣẹlẹ pajawiri ti ṣe abẹwo sibẹ, wọn si ti ṣe agbeyẹwo awọn dukia to padanu.

AWIKONKO gbọ pe ṣọọbu ti ko din ni mẹẹdogun ni ijamba ọhun gbe lọ, to si fi ọja olowo iyebiye ṣofo danu. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI