Ẹgbẹ awọn aṣojukọroyin lorileede Naijiria, ẹka ti ipinlẹ Kwara ti gbe awọọdu nla, alailẹgbẹ fun Gomina ipinlẹ naa, AbdulRahman AbdulRazaq lori awọn ipa rere ati idagbasoke alailẹgbẹ to n mu ba ipinlẹ naa.
Ọjọbọ, Tọside to kọja yii la gbọ pe awọn aṣojukọroyin naa ti a mọ si NUJ Correspondent's Chapel fun gomina ni awọọdu nla naa ti wọn pe ni "Human Capital Development Advocate Award" niluu Ilọrin to jẹ olu ilu ipinlẹ ọhun.
Nigba to n fi imọriri rẹ han si awọọdu yii, igbakeji gomina, Kayọde Alabi to ṣoju ọga rẹ, sọ pe idunnu nla lo jẹ f'oun wi pe oun gba awọọdu naa, nitori pe ko wọpọ ki awọn akọroyin maa fun gomina wọn laami ẹyẹ.
Gomina AbdulRazaq wa sọ pe oun fi awọọdu naa jin fun gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara, nitori pe awọn ni wọn jẹ ki aami ẹyẹ naa tọ s'oun, nipa gbigbe oun de ipo naa.
No comments:
Post a Comment