Portable, Were olorin yọju s’awọn ọlọpaa l’Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, July 1, 2022

Portable, Were olorin yọju s’awọn ọlọpaa l’Ogun


Ohun ti ọpọ awọn eeyan ti n sọ tẹlẹtẹlẹ ni pe gbajugbaja onkọrin takasufee nni, Habib Okikiọla, ti ọpọ awọn eeyan mọ si Portable ko ni i yọju s’awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun n’igba ti wọn ranṣẹ si i pe ko yọju si wọn, lati le sọ t’ẹnu rẹ, lori bo ṣe ni ki awọn ọmọ ẹyin rẹ lu ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni DJ Chicken nilukulu.

Portable la gbọ pe o paṣẹ ki awọn ọmọ ẹyin rẹ lu DJ Chicken toun naa n tẹle e lẹyin, lori awọn ẹsun ijẹnilẹyin to fi kan an, to si tun gbe e sori ikanni ayelujara lati jẹ ki gbogbo aye mọ si.

Fọnran naa lo tẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun lọwọ, ti kọmiṣanna wọn, Lanre Bankọle fi ranṣẹ pe e lati wa sọ idi to fi le huwa naa.

Wẹrẹ ni wọn sọ pe Portable lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to wa lagbegbe Eleweran niluu Abẹokuta, nibi to ti lọ jọwọ ara rẹ.

Portable, to tun maa n pe ara rẹ ni Were Olorin la gbọ pe o lọ sibẹ pẹlu manija rẹ ati baba rẹ.

Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa to f’idi rẹ mulẹ fun wa sọ pe Portable ti ṣalaye ọrọ tiẹ, idi to fi ni ki wọn lu DJ Chicken.

O wa sọ pe ẹsun ti wọn fi kan Portable ki i ṣe ẹṣẹ nla kan, idi to fi ni anfaani wa lati gba beeli ẹ, eyi ti awọn eeyan rẹ ti ṣe pẹlu oniduro to ṣe e f’ọkan tan. O ni oniduro Portable ti ṣe ileri wi pe yoo yọju si wọn nigbakugba ti wọn ba ranṣẹ pe e.

Oyeyẹmi ti wa sọ pe awọn n reti DJ Chicken lagọ wọn, koun naa wa ṣalaye ohun to ṣẹlẹ, lati le mọ igbesẹ to kan labẹ ofin.

A gbọ pe bi Portable ṣe yọju si agọ ọlọpaa ko ṣẹyin ere kan to ni pẹlu awọn ololufẹ rẹ niluu Abẹokuta lonii, ọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun 2022, nibi ti wọn lo ṣee ṣe k’awọn ọlọpaa lọ fi ọwọ ofin gbe e nibẹ.

Wọn ni Portable ko fẹ ki awọn ọlọpaa wa yẹyẹ oun loju gbogbo aye, lo jẹ ko sare lọ yọju si wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI