Gómìnà AbdulRazaq gba àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera mẹ́tàdínnígba síṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ní Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 3, 2022

Gómìnà AbdulRazaq gba àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera mẹ́tàdínnígba síṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ní Kwara


Ṣe ni gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara lọ gba ilu, ati oniruuru ohun elo orin, ti wọn si n kọrin ọpẹ kaakiri ipinlẹ naa lori bi Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe bu ọwọ lu igbanisiṣẹ awọn oṣiṣẹ eleto ilera ti ko din ni mẹtadinnigba (197) kaakiri ipinlẹ naa.

Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Sa'as Aluko, ẹni to jẹ alakoso agba fun gbogbo ọsibitu kaakiri ipinlẹ Kwara, iyẹn Kwara State Hospital Management Board fi sita lonii, ọjọ Aiku, Sannde lo ti jẹ ko di mimọ pe awọn dọkita, nọọsi, oludamọran ko gbẹyin ninu awọn oṣiṣẹ eleto ilera ti gomina bu ọwọ lu lati bẹrẹ iṣẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Gomina AbdulRazaq bu ọwọ lu awọn eeyan naa pẹlu erongba lati tubọ mu idagbasoke ba ẹka eto ilera nipinlẹ naa.

Oludamọran (Consultant) mẹjọ (8), dọkita mẹtalelogun (23), nọọsi mejilelaadọrin (72), at'awọn miran ni oniruuru ẹka eto ilera la gbọ pe gbogbo wọn wa.

Awọn mi in ni Senior Registrar mẹta, Pharmacy Technicians mẹtala, Pharmacists mẹfa, Medical Laboratory Scientists mẹrin, Scientific Officers marun-un, Community Health Extension Workers (CHEW) ogun, Junior CHEW ogun, ati Hospital Attendants mẹtalelogun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI