Lọjọ Aje, Mọnde ana ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe abẹwo si gbọngan aṣa igbafẹ nla, ẹlẹẹkeji iru rẹ lẹkun aarin gbungbun Ariwa orileede yii, eyi ti wọn n kọ lọwọ.
Gbọngan aṣa igbafẹ nla ọhun, iyẹn 'Ilọrin Visual Arts Centre', la gbọ Gomina AbdulRazaq ṣe agbatẹru rẹ lati fi fa oju awọn eeyan kaakiri agbaye mọra lati maa fi pawo wọle s'apo ijọba.
AbdulRazaq to kọwọrin pẹlu kọmiṣanna f'ọrọ eto iroyi, Ọnarebu Ọlabọde Towoju nigba to n sọrọ jẹ ko di mimọ pe akọkọ iru rẹ, iyẹn (first purpose-built contemporary film and art institute) nilẹ Afrika.
Bakan naa lo ni gbọgan yii ni yoo jẹ ẹlẹẹkeji iru ẹ, (second Dolby Atmos Certified film production studio) ni ẹkun naa.
AbdulRazaq ni ki i ṣe pe awọn eeyan yoo maa wa sibẹ nikan lati gbafẹ, ti wọn yoo si tun ronu nnkan gidi, bi ko ṣe pe yoo tun pese iṣẹ f'awọn ọdọ ti wọn ko ni iṣẹ lọwọ, fun idagbasoke.
No comments:
Post a Comment