Ẹ dákẹ́ rúmọ́ọ̀sì! Ìjọba kò jẹ ọlọ́pàá kankan lówó oṣù o - ilé-iṣé ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 21, 2022

Ẹ dákẹ́ rúmọ́ọ̀sì! Ìjọba kò jẹ ọlọ́pàá kankan lówó oṣù o - ilé-iṣé ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti sọ pe ki gbogbo awọn to n gbe iroyin ti ko tọ kaakiri ipinlẹ naa dẹkun, nitori pe iroyin to jinna si otitọ ni.

Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọkassnmi Ajayi gbe jade lopin ọsẹ to kọja yii, o jẹ ko di mimọ pe awọn ọlọpaa agbegbe ti wọn da silẹ lati fi ṣe iranwọ 

Bẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii ni fọnran kan jade sita nibi ti awọn ọlọpaa kan ti n fi ẹhonu han pe ijọba ipinlẹ Kwara ko san owo oṣu fun wọn lati bi ọdun kan sẹyin, ti fọnran naa si kaakiri gidi.

Alukoro ọlọpaa sọ pe awọn to ṣe ifẹhonuhan naa kii ṣe ojulowo ọlọpaa, bi ko ṣe pe awọn ọlọpaa ti wọn da silẹ fun iṣẹ ọlọpaa agbegbe nipinlẹ Kwara ni, lati maa ran awọn ojulowo ọlọpaa lọwọ.

O ni awọn ọlọpaa agbegbe ọhun ko si ninu ilana sisan owo oṣu fun wọn, ṣugbọn to sọ pe ijọba ti pe wọn lati ni asọyepọ pẹlu wọn.

Ọga ọlọpaa, Tuesday Assayomo ti wa f'idi rẹ mulẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko jẹ oṣiṣẹ kankan lowo oṣu, to si ni ki awọn eeyan ma ṣe gba fọnran naa gbọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI