2023: Awọn agbaagba Fulani fẹẹ ṣepade pẹlu Tinubu ati Atiku - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 12, 2022

2023: Awọn agbaagba Fulani fẹẹ ṣepade pẹlu Tinubu ati Atiku


A gbọ pe gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ẹgbẹ awọn agbaagba ẹya Fulani lati ṣe ipade papọ pẹlu awọn ondije-dupo aarẹ orileede yii meji nni, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu to n jade labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ati Alaaji Atiku Abubakar toun naa jade labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP.
 
Ohun ti a gbọ ni pe ko si nnkan meji to fa bi awọn agbaagba Fulani naa ṣe fẹẹ ṣe ipade papọ pẹlu mejeeji wọnyi, bi ko ṣe ti awọn awuyewuye ati wahala to n waye nipa b'awọn erongba wọn lati di aarẹ orileede Naijiria lọdun 2023 to n bọ.
 
Awọn ẹgbẹ naa labẹ aburada ẹgbẹ Fulani Development Association of Nigeria, ni wọn sọ eyi di mimọ niluu Abuja, lopin ọsẹ to kọja yii, iyẹn nibi ti wọn ti bura f'awọn oloye ẹgbẹ tuntun ti wọn yan.
 
Wọn ni ipade naa ni yoo sọ ẹni ti wọn yoo tẹle ninu idibo ọdun 2023 to n bọ, iyẹn bi eyikeyi ninu wọn ba fi ara mọ awọon ilana ti wọn yoo kalẹ fun wọn.
 
Aarẹ ẹgbẹ naa lapapọ, Muhammad Bello, sọ pe awọn ti gbaradi lati ba awọn oludije mejeeji sọrọ, awọn yoo si tẹle ẹni to ba ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu wọn lori awọn nnkan ti wọn ba n fẹ, yala ni ti Fulani, Igbo, Yoruba, Kanuri tabi Hausa.
 
Bakan naa ni wọn sọ pe o ti pẹ ti ẹya Fulani ti n gbe laaarin awọn ẹya miran, ṣugbọn lojiji ni wahala dide si wọn nigba ti awọn ẹya yooku bẹrẹ sii  ni ipinu loriṣiriṣi, eyi to sọ ibagbepọ alaafia di nnkan miran.
 
Bello sọ pe ohun to tubọ n ṣe akoba fun awọn Fulani wọn ni wọn ko ṣe kawe, eyi to ba eto aabo Naijiria, ati pe awọn ni lati ṣe idanilẹkọọ f'awọn eeyan nipa awọn Fulani.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI