Ẹgbẹ oṣelu APC ni Kwara ti bẹrẹ sii da owo awọn adije to padanu pada fun wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 12, 2022

Ẹgbẹ oṣelu APC ni Kwara ti bẹrẹ sii da owo awọn adije to padanu pada fun wọn


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC n'ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn ti bẹrẹ sii da gbogbo owo t'awọn ondije du ipo ti wọn ti padanu ninu idibo abẹlẹ pada fun wọn, lati le gba laafia laaye.

Wọn ni ọna lati le tu gbogbo awọn oludije naa ti inu n bi lọkan, lo fa a ti wọn fi gbe igbesẹ naa, paapaa lati le jẹ ki ẹgbẹ naa wa ni iṣọkan ati ifẹ.

Alaga ẹgbẹ APC n'ipinlẹ naa, Ọmọọba Sunday Fagbemi, nigba to n sọrọ ninu ifọrọwerọ kan to ṣe lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii sọ pe awọn oludije s'ipo oṣelu kereje l'awọn fẹẹ ṣe iranwọ fun, ko maa ba a dabi ẹni pe wọn padanu patapata.

O ni gbogbo eto ati ilana lawọn ti fi si ojuṣe lati rii pe wọn dun gbogbo eeyan ninu patapata, lai ni ikunsinu kankan mọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI