Baba mi l'ẹni akọkọ ti maa kọkọ pa, mo ti n jale tipẹ - Hassan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, September 11, 2022

Baba mi l'ẹni akọkọ ti maa kọkọ pa, mo ti n jale tipẹ - Hassan


Epe rabandẹ-rabandẹ l'awọn to gbọ si iṣẹlẹ naa n ṣe fun gendekunrin kan, Ibrahim Hassan to ṣeku pa baba rẹ, ẹni aadọrun ọdun laipẹ yii, ti wọn si rawọ ẹbẹ pe niṣe lo gbọdọ jiya ẹṣẹ rẹ i kikun.
 
Hassan nigba to n sọrọ niwaju awọn akọroyin sọ pe iṣẹ eṣu ni boun ṣe pa baba oun danu, toun si tun na papa bora.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Abẹrẹ iku ni mo gun baba mi, mo si tun fun baba mi lọrun pa, ko to di pe mo lọ sin wọn sinu igbo kan, ki aṣiri ma ba a tu.

"Ko si nnkan meji to jẹ ki n pa baba mi to kọja owo ti mo ri ninu apo ile ifowopamọ wọn ni banki, mo si pinnu lati ji ẹrọ igbalode ti wọn fi n gba owo lẹnu ẹrọ, iyẹn ATM wọn gbe.

"Igba akọkọ ree ti maa paayan laye mi, mo t n jale tipẹ, mi o si le ka iye igba ati akoko ti mo ti jale latigba ti mo ti bẹrẹ ni kikun.
 
"Mo ti ji aṣọ gbe ri nigba kan, to jẹ pe ẹgbọn mi ni wọn fi iya rẹ jẹ, nigba to wọ aṣọ naa jade lọjọ ti mo jiigbe.

"Mo kabamọ awọn iwa mi, mo si mọ pe o ti tan fun mi patapata bayii. Mo ti jiya gidi sẹyin, mo si mọ pe bi mo ba ṣi wa laye, awọn ọmọ naa yoo ṣe iru nnkan ti mo ṣe yii fun mi."
 
Agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ajayi Ọkasanmi, nigba to n sọrọ ni olu ileeṣẹ ọlọpaa jẹ ko ye wa pe Ibrahim pa baba rẹ, Oloogbe Ibrahim to jẹ ajagunfẹyinti lọdun 1990s.

O ni aditu ti iku baba naa jẹ, lo mu k'awọn bẹrẹ iwadii, paapaa nigba ti ọkan lara awọn ọmọ baba naa, Aishat Ibrahim wa fi ẹjọ sun pe ẹnikan ti ṣeku pa baba awọn.

Lẹyin ọpọlọpọ iwadii, ni aṣiri tu pe ẹni to ṣeku pa baba naa n jaye familekintutọ nipinlẹ Kaduna, eyi lo jẹ ki wọn gbera lọ sibẹ, ti ọwọ si tẹ Hassan.
 
Ni bayii, Hassan yoo foju ba ile-ẹjọ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI