Ẹni to mọ oṣelu gidi lo yẹ ka maa tẹle - KPMO sọ f'awọn alatako AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, September 11, 2022

Ẹni to mọ oṣelu gidi lo yẹ ka maa tẹle - KPMO sọ f'awọn alatako AbdulRazaq


Ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni Kwara Progressive Media Organization, KPMO ti gba awọn oloṣelu, paapaa awọn alatako Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara lamọran lati yee ṣe oṣelu ẹtanu, ati pe iru oloṣelu bii gomina lo yẹ ki wọn maa tẹle fun ọjọ iwaju rere.
 
Wọn ni ki gbogbo awọn to wa ninu ẹgbẹ alatako dẹkun lati maa ṣe oṣelu ẹtanu, bi ko ṣe pe ki wọn rẹ ara wọn silẹ lati mu idagbasoke ba oṣelu awaarawa, eyi ti yoo daabo bo ẹmi ati dukia araalu ninu eto idibo ọdun 2023.

Ninu atẹjade ti oludasilẹ ẹgbẹ naa, Usman Lade fi sita lo ti gba wọn lamọran lati tẹle ilana oṣelu Gomina Abdulrahman Abdulrazaq, ẹni to ti n gba alaafia, ifẹ ati iṣọkan laayeni gbogbo igba.

Laipẹ yii, Ọmọwe Bukọla Saraki to jẹ olori ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party, PDP n'ipinlẹ Kwara ninu fọnran kan to gbe jade, ni wọn lo ti paṣẹ fun gbogbo awọn ọmọ ẹyin rẹ lati maa wa ọna ti wọn yoo fi ba ijọba to wa nita jẹ, eyi ti ko ni fun un lanfaani lati pada sipo lẹẹkeji.
 
Lade sọ pe iwa ti ko bojumu, ti ko si fẹ ọjọ iwaju rere fun ipinlẹ naa ni Saraki n hu kaakiri, eyi ti ko yẹ fun iru eeyan to ti di ipo nla mu lorileede yii.

O ni oloṣelu bii ti Aṣofin Bukola Saraki, at'awọn ọmọ ẹyin rẹ ni lati maa ṣọra nipa iwa ati isọrọsi i wọn, paapaa ninu iwe iroyin ati nita gbangba, ki wọn ma ba a dana sun pẹpẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI