Baba ọlọmọ mẹfa fipa ba ọkan lara awọn ọmọ ẹ laṣepọ l'Abẹokuta, o tun n f'iku halẹ mọ-ọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 12, 2022

Baba ọlọmọ mẹfa fipa ba ọkan lara awọn ọmọ ẹ laṣepọ l'Abẹokuta, o tun n f'iku halẹ mọ-ọn


"Mi o mọ nnkan to ko si mi lori, ṣe lo dabi asasi fun mi lọjọ naa. Ẹ ṣaanu mi, iṣẹ eṣu ni, mi o mọ pe aṣiri maa tu." Wọnyi lọrọ ti baale ile, ẹni ọdun mẹrindinlaadọta kan, Oluṣẹgun Oluwọle to fipa ba ọmọ rẹ, ọmọ ọdun mẹtadinlogun laṣepọ niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Aarin oru, lakoko ti gbogbo awọn eeyan ti lọ sun, la gbọ pe Oluṣẹgun dide lati fipa ba ọmọ rẹ naa laṣepọ.
 
Iya ọmọ naa la gbọ pe o gba teṣan ọlọpaa Ibara lọ lati lọ fi ẹjọ sun nibẹ, ko to di pe wọn sare lọ gbe e.
 
Bi wọn ṣe gbe e, ni iroyin fi to wa leti pe Oluṣẹgun ti bẹrẹ si i ka boroboro, to si n bẹbẹ pe ki wón foju aanu wo oun, ati pe iṣẹ eṣu ni.
 
Ni bayii, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki wọn tubọ ṣe iwadii ọkunrin naa daadaa, ko to di pe wọn foju rẹ ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI