Olori awọn adigunjale l'Anambra, atawọn ọdaran mẹrin miran ti ha - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 12, 2022

Olori awọn adigunjale l'Anambra, atawọn ọdaran mẹrin miran ti ha


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra ti rọwọ to olori awọn adigunjale to maa n digun ja awọn eeyan lole lopopona Ufuma – Oko – Uga- Amaokpala to wa l'awọn ijọba ibilẹ Orumba North ati Aguata.

Agbṣnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Toochukwu Ikenga lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi sita wi pe b'ọwọ ṣe tẹ olori wọn naa, lawọn ọmọ ẹyin rẹ ti salọ.

Ikenga, ninu atẹjade naa sọ pe olori awọn adigunjale ọhun ti jẹwọ pe ogbologbo adigunjale loun, ati pe oun lẹni to lewaju ikọ adigunjale to lọ kọlu otẹẹli kan to wa lagbegbe Ndikelionwu,  nibi ti wọn ti fipa ba ọmọbinrin kan to jẹ oṣiṣẹ ibẹ laṣepọ.

O sọ pe ọjọ kẹfa, oṣu kẹsan ni ọwọ tẹ Okechukwu Okpo, ọmọ ọdun mẹrinlelogun to wa lati abule Ndobasi, ipinlẹ Ẹbọnyi. O ni ibọn ilewọ kan ni wọn ka mọ-ọn lọwọ ni kete tọwọ palaba ẹ segi.

Agbẹnusọ naa sọ pe bi wọn ṣe foju kan awọn ọlọpaa ni wọn ṣina ibọn bolẹ fawọn ọlọpaa, ṣugbọn ti wọn pada juba ehoro nigba ti wón rii pe agbara wọn ko ka a.

Idigunjale ti ko din ni marundinlọgbọn la gbọ pe wọn ti kopa, ti wọn tun ti ji awọn eeyan gbe, pẹlu gbigba mọto lopopona marosẹ Oko Ufuma, Uga, Amaokpala atawọn ibomiran.
Yatọ si eyi, Ikenga tun jẹ ko di mimọ pe ọwọ tun tẹ awọn mẹrin miran ti wọn fura si pe ọdaran ni wọn. Agbegbe ọtọọtọ lo ni ọwọ ti tẹ awọn mẹrẹẹrin.

Awọn mẹrin naa ni Chukwubike Anieto, ọmọ ogun ọdun lati Agulu; Chukwuemerie Ike, ọmọ ọdun mẹrindinlogoji lati Agulu; Chidera Muo, ọmọ ọdun marundinlọgbọn lati Neni, ati Chukwuma Israel, ọmọ ọdun mejidinlọgbọn lati agbegbe Umuezeani to wa ni abule Akwaeze.
 
Gbogbo wọn pata lo sọ pe wọn yoo foju winna ofin laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI