Messi ti n palẹmọ lati fi ẹgbẹ agbabọọlu PSG silẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 28, 2022

Messi ti n palẹmọ lati fi ẹgbẹ agbabọọlu PSG silẹ


Bi iroyin to tẹ wa lọwọ laipẹ yii nipa gbajugbaja agbabọọlu ọmọ orileede Argentina nni, Lionel Messi ba fi jẹ otitọ, a jẹ pe ọkunrin naa to n gba bọọlu fun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Paris Saint-German, PSG ti n palẹmọ lati fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ.

Ohun ti a gbọ ni pe gbogbo eto lo ti fẹẹ pari fun Messi lati kede inu ẹgbẹ agbabọọlu miran to tun fẹẹ lọ darapọ mọ.

Wọn ni lẹyin ti idije ifigagbaga ife ẹyẹ agbaye, iyẹn 2022 World Cup ba waye ni Messi yoo mọ ohun to fẹẹ ṣe ni pato.

Bẹ o ba gbagbe, iwe adehun ọlọdun meji ni Messi tọwọ bọ pẹlu PSG lọdun 2021 to kọja, ati pe ni bayii, ko tii si ẹgbẹ agbabọọlu kankan ti wọn ṣi n foju sọna lati ra a.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI