Keresimesi: AbdulRazaq san owo oṣu kejila, ajẹẹlẹ, ifẹhinti fawọn oṣiṣẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 20, 2022

Keresimesi: AbdulRazaq san owo oṣu kejila, ajẹẹlẹ, ifẹhinti fawọn oṣiṣẹ


Bi ayẹyẹ ọdun keresimesi ati ọdun tuntun ṣe ti sunmọ etile, ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti san owo oṣu gbogbo oṣiṣẹ patapata.

Yatọ si owo oṣu awọn oṣiṣẹ fun oṣu kejila ti a wa yii, gomina tun san owo ifẹhinti awọn oṣiṣẹ fẹyinti, to fi mọ gbogbo ẹtọ patapata.

Awọn ti wọn fẹyinti laaarin ọdun 2009 ati 2010 ni ipinlẹ Kwara bu ọwọ lu owo ifẹhinti ati owo to jẹ ẹtọ wọn patapata, paapaa awọn oṣiṣẹ fẹyinti nijọba ibilẹ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI